Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 22, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Látinú Ẹ̀wọ̀n Sínú Má Jáde Nílé

Látinú Ẹ̀wọ̀n Sínú Má Jáde Nílé

Méjì lára àwọn arákùnrin tí wọn ò jẹ́ kí wọ́n jáde nílé rèé pẹ̀lú àwọn agbẹjọ́rò wọn. Láti ọwọ́ òsì sí ọ̀tún: agbẹjọ́rò Vitaly Svintsov, Vladimir Kochnev, Aleksandr Suvorov àti agbẹjọ́rò Egiazar Chernikov.

Ní August 3, 2018, Adájọ́ Inna Yangubayeva tó wà ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Leninsky ti ìlú Orenburg, lórílẹ̀-èdè Rọ́síà, dájọ́ pé kí wọ́n má jẹ́ kí Arákùnrin Vladimir Kochnev àti Arákùnrin Aleksandr Suvorov jáde nílé wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ti lo ọjọ́ méjìdínlọ́gọ́rin (78) lẹ́wọ̀n. Lọ́jọ́ kan náà, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Magadan ní kí wọ́n má jẹ́ kí Arákùnrin Konstantin Petrov jáde nílé mọ́, bẹ́ẹ̀ òun náà ti lo ọjọ́ mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64) látìmọ́lé. A dúpẹ́ pé àwọn ará wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ò sí lẹ́wọ̀n mọ́, àmọ́ ẹjọ́ wọn ò tíì parí, tí wọ́n bá sì dá wọn lẹ́bi, wọ́n lè rán wọn lọ́ sẹ́wọ̀n nǹkan bí ọdún mẹ́wàá.

Títi di August 16, àwọn ará wa mẹ́sàn-án ni wọn ò jẹ́ kí wọ́n jáde nílé mọ́, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sì wà lẹ́wọ̀n káàkiri ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Àwọn ọgbọ̀n (30) míì tún wà lára àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti mú kí wọ́n tọwọ́ bọ̀wé pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé wọn láìgba àyè lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìlú. Ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fún àwọn ará wa tó ń kojú wàhálà tó bani lẹ́rù yìí nílẹ̀ Rọ́ṣíà.​—2 Kọ́ríńtì 1:11.