Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 7, 2016
RỌ́ṢÍÀ

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Fẹ́ Ṣe Ohun tí Ò Ṣẹlẹ̀ Rí, Wọ́n Fẹ́ Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Náà Pa

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Fẹ́ Ṣe Ohun tí Ò Ṣẹlẹ̀ Rí, Wọ́n Fẹ́ Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Náà Pa

ÌLÚ ST. PETERSBURG, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà—Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fẹ́ ṣe ohun tí ò ṣẹlẹ̀ rí, wọ́n ń halẹ̀ pé àwọn máa ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pa.

Ní March 2, 2016, Agbẹjọ́rò Àgbà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kọ lẹ́tà láti kìlọ̀ pé tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ò bá wá nǹkan ṣe sí “ẹrù òfin” tí ìjọba kà sí ti “agbawèrèmẹ́sìn” láàárín oṣù méjì, “wọ́n máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa pa.” Yaroslav Sivulskiy, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nìkan ni ìgbésẹ̀ yìí máa kàn, wọ́n á tún gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun tá a ní, wọ́n á wá fòfin de ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò Rọ́ṣíà.”

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.

Ìgbà tí ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nílẹ̀ Rọ́ṣíà tá a ti kọ́kọ́ forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ni wọ́n fẹ́ ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa yìí, torí March 27, 1991 la kọ́kọ́ forúkọ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin, a sì tún ìforúkọsílẹ̀ náà ṣe ní April 29, 1999. Ṣe ni ìjọba tún gbé tuntun dé lórí bí wọ́n ṣe ń fínná mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ìhàlẹ̀ tí wọ́n ń ṣe pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní abúlé Solnechnoye, nǹkan bíi máìlì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) lápá àríwá ìlú St. Petersburg lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Lọ́dún tó kọjá, ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó ìtẹ̀jáde wọn wọ orílẹ̀-èdè náà, títí kan Bíbélì lédè ilẹ̀ Rọ́ṣíà, wọ́n sì fòfin de ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org. Bẹ́ẹ̀, Rọ́ṣíà nìkan ni orílẹ̀-èdè tó fòfin de ìkànnì yìí ní gbogbo ayé. Ọ̀gbẹ́ni Sivulskiy sọ pé, “Àṣìlò òfin ló mú kí wọ́n máa fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sì gbà bẹ́ẹ̀. A fẹ́ máa ṣe ìjọsìn wa ní ìrọwọ́rọsẹ̀, ká sì máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìsí ìdíwọ́ bá a ṣe ń ṣe láti ọdún márùndínláàádóje (125) sẹ́yìn lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.”

Ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ò yé fínná mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tó sì sábà ń fà á ni bí ìjọba àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀. Àwọn oníròyìn kárí ayé jábọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí pé ohun tí ìwé ìròyìn The New York Times pè ní “àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín ìjọba àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà,” ló dà bíi pé ó ń rúná sí bí ìjọba ṣe ń fínná mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ń fi òfin ká àwọn àtàwọn ẹ̀sìn kéékèèké míì nílẹ̀ Rọ́ṣíà lọ́wọ́ kò. Iléeṣẹ́ ìròyìn Associated Press jábọ̀ pé ìgbésẹ̀ tí ìjọba “ń gbé nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún dẹ́rù ba àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.” Ìròyìn láti iléeṣẹ́ Reuters fi hàn pé “àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ àwọn míì tí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń fòfin dè pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn” ni wọ́n ń firú ìyà yìí jẹ. Ní December 2015, ìwé ìròyìn The Independent sọ pé ìdí tí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà fi ṣòfin náà ni kí wọ́n lè “dènà àwọn apániláyà àtàwọn tó ń hùwà ipá torí wọ́n ń fẹ́ òmìnira lójú méjèèjì.” Àmọ́ bí ìwé ìròyìnThe Huffington Post ṣe sọ ní March 20, 2016, wọ́n ti wá ń lo òfin yìí “láti fẹ̀sùn kan àwọn ẹlẹ́sìn àlàáfíà,” bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń sapá kí àwọn ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè náà àti Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lé bá wọn wá nǹkan ṣe sí i, ìwé ìròyìn The Moscow Times tó jáde ní March 25, 2016 sọ pé ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti ṣòfin tuntun “tó fún àwọn ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lẹ́tọ̀ọ́ láti gbá ìpinnu tí àwọn ilé ẹjọ́ àgbáyé ṣe dà nù.”

Àwọn àlejò tó wá sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Rọ́ṣíà láti ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ tó dá lórí Bíbélì fáwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tún máa ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n sì máa ń kàn sí wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó dín ẹgbẹ̀rún márùn-ún (175,000) ló wà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, gbogbo àwọn èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà sì lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́jọ (146,000,000).

David A. Semonian tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ní oríléeṣẹ́ wa nílùú New York sọ pé: “Ó yà wá lẹ́nu gan-an pé ìjọba lè halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Rọ́ṣíà pa. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ń fara balẹ̀ retí ohun tó máa tìdí ọ̀rọ̀ yìí yọ.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, tel. +7 812 702 2691