OCTOBER 4, 2017
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹ̀jọ́ Kò-tẹ́-mi-lọ́rùn Sọ Pé Dennis Christensen Ṣì Máa Wà Látìmọ́lé Títí Dìgbà Tí Wọ́n Máa Fi Parí Ẹjọ́ Rẹ̀
NÍ SEPTEMBER 28, 2017, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi wákàtí mẹ́ta gbọ́ ẹjọ́ kò-tẹ́mi-lọ́rùn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Dennis Christensen, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ilé ẹjọ́ tí wọ́n ń pè ní Oryol Regional Court kọ̀ jálẹ̀ láti fi arákùnrin wa tó jẹ́ ọmọ ìlú Denmark yìí sílẹ̀. Wọ́n sọ pé ó máa wà látìmọ́lẹ̀ títí di November 23, 2017 tí wọ́n máa dá a lẹ́jọ́.
Nígbà tí ilé ẹ̀jọ́ àdúgbò kan ń gbọ́ ẹjọ́ Ọ̀gbẹni Christensen ní ọsù July, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ sún ìgbẹ́jọ́ náà sí oṣù November, a sì gbà pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ fi àkókò yẹn wá oríṣiríṣi ẹ̀sùn sí arákùnrin wa yìí lẹ́sẹ̀, kí wọ́n lè dá a lẹ́jọ́ agbawèrèmẹ́sìn. Agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Christensen ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn ECHR. Láti September 4, 2017 sì ni ilé ẹjọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí tó yẹ, wọ́n si ti bi ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní àwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó mú kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ Ọ̀gbẹ́ni Christensen dù ú.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló fẹ́ mọ ibi tí ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Christensen máa já sí, torí pé ayé ìgbà tí ìjọba Soviet ń ṣàkóso ló ti ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn pé kí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ju ẹnì kan sẹ́wọ̀n nítorí ẹ̀sìn tó ń ṣe.