Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 11, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ní Rọ́ṣíà Fẹ́ Kí Wọ́n Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Ní Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Ní Rọ́ṣíà Fẹ́ Kí Wọ́n Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Ní Rọ́ṣíà

Ní December 7, 2017, ilé ẹjọ́ Sestroretskiy District Court wọ́gi lé àdéhùn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láṣẹ láti lo Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Tó bá jẹ́ pá bákan náà lọ̀rọ̀ rí lẹ́yìn tá a bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, a jẹ́ pé òfin gba ìjọba Rọ́ṣíà láyè láti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé tó wà ní Solnechnoye, nítòsí ìlú St. Petersburg.

Ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sẹ́yìn ni ilé náà di ti àjọ kan tó forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania (WTPA), wọ́n sì fìdí àdéhùn náà múlẹ̀ lábẹ́ òfin, ìjọba Rọ́ṣíà náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. WTPA ní kí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Rọ́ṣíà máa lo ilé náà láti darí iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè yẹn, wọ́n sì ń san owó orí tó yẹ kí wọ́n san.

Torí ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe ní April 20, 2017, pé àwọn fòfin de àwọn àjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí ń lò àtí pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa àti àwọn ilé wa, agbẹjọ́rò fún ìjọba sọ pé àdéhùn ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] tó wà láàárín àjọ WTPA àti ìjọba ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òfin sọ pé tí iye ọdún kan pàtó ba ti kọjá, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yí irú àdéhùn yìí pa dà. Tipẹ́tipẹ́ sì ni iye ọdún yìí ti kọjá fún àdéhùn tí agbẹjọ́ro ní kí wọ́n yí pa da yìí. Lẹ́yìn wákàtí mẹ́rin tá a fi fi àwọn ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ han ilé ẹjọ́ pé àdéhùn náà ṣì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ó sì bófin mu, Bogdanova tó jẹ́ adájọ́ ṣe ìdájọ́ tó bá ohun tí agbẹjọ́rò fún ìjọba fẹ́ mu.

A ò ní ju ọgbọ̀n [30] ọjọ́ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.