APRIL 5, 2017
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ṣì Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Táwọn Aláṣẹ Fẹ́ Fòfin Dè ní Rọ́ṣíà
Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti gbọ́rọ̀ lọ́tùn-ún lósì lórí ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn aláṣẹ fẹ́ fòfin dè, Ilé Ẹjọ́ náà ní kí wọ́n dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró díẹ̀. Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ló fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ “kéde pé agbawèrèmẹ́sìn ni Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀, kí wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé e.” Ìgbẹ́jọ́ náà máa pa dà bẹ̀rẹ̀ ní April 6, 2017, ní aago méjì ọ̀sán.
Mark Sanderson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tóun náà wà níbi ìgbẹ́jọ́ náà, sọ pé: “Ó bani nínú jẹ́ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ò fara mọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú ohun tí àwọn aṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà sọ, tí wọ́n sì fagi lé e. Àwọn aṣojú oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè àtàwọn iléeṣẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn náà wà níbi ìgbẹ́jọ́ yìí. Ó dáa bó ṣe jẹ́ pé gbogbo ayé ló ń retí ohun tó máa tẹ̀yìn ẹjọ́ yìí yọ.”