Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 12, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Gbọ́rọ̀ Lẹ́nu Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórí Bí Àwọn Aláṣẹ Ṣe Fẹ́ Fòfin Dè Wọ́n

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Gbọ́rọ̀ Lẹ́nu Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórí Bí Àwọn Aláṣẹ Ṣe Fẹ́ Fòfin Dè Wọ́n

April 12, 2017 ni ọjọ́ kẹrin tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn aláṣẹ fẹ́ fòfin dè ní Rọ́ṣíà. Àwọn agbẹjọ́rò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ tẹnu wọn, wọ́n sọ pé ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ ta ko àdéhùn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tọwọ́ bọ̀ lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀, ó sì ta ko òfin ilẹ̀ tiwọn fúnra wọn.

Àwọn agbẹjọ́rò náà sọ pé ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ, pé kí wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ta ko òfin ìjọba àpapọ̀, títí kan ìwé àdéhùn European Convention àti International Covenant on Civil and Political Rights. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé àdéhùn yẹn, títí kan òfin ilẹ̀ Rọ́ṣíà fúnra rẹ̀, fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lómìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti òmìnira láti kóra jọ pẹ̀lú àwọn míì (ẹ̀tọ́ láti forúkọ ẹ̀sìn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, káwọn ẹlẹ́sìn sì máa kóra jọ).

Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin ló jẹ́rìí sí i pé ìjọ àwọn kì í lo àwọn ìtẹ̀jáde tí ìjọba ti fòfin dè pé wọ́n jẹ́ ti agbawèrèmẹ́sìn, àti pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn lọ́nàkọnà. Ilé Ẹjọ́ ti dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró fúngbà díẹ̀, wọ́n sì ti sún un di April 19, 2017, ní aago mẹ́wàá àárọ̀.