Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 30, 2016
RỌ́ṢÍÀ

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Sọ Pé Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ń Lo Òfin Láti Fẹ̀sùn Agbawèrèmẹ́sìn Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Sọ Pé Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ń Lo Òfin Láti Fẹ̀sùn Agbawèrèmẹ́sìn Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

ÌLÚ ST. PETERSBURG, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà—Ọdún 2016 ló pé ọdún márùndínláàádóje (125) táwọn lọ́balọ́ba lé Ọ̀gbẹ́ni Semyon Kozlitskiy kúrò nílùú torí pé ó ń wàásù nípa ohun tó wà nínú Bíbélì. Ọ̀gbẹ́ni yìí wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ wà ní Rọ́ṣíà. Lọ́dún 1891, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n de Ọ̀gbẹ́ni Kozlitskiy, wọ́n sì mú un lọ sí Siberia láìjẹ́ kó fojú ba ilé ẹjọ́, ibẹ̀ ló sì wà títí tó fi kú lọ́dún 1935.

Bí Rọ́ṣíà ṣe ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ọgọ́rùn-ún ọdún tó ti kọjá ò tíì yí pa dà. Ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò yé “ṣèdíwọ́ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, . . . àti òmìnira ẹ̀sìn, pàápàá fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn míì.”

Ọ̀gbẹ́ni Heiner Bielefeldt tó jẹ́ Aṣojú Pàtàkì fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn tàbí ohun téèyàn gbà gbọ́.

Ó di dandan pé kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn máa rí sí i pé àwọn orílẹ̀-èdè tó fọwọ́ sí àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights (ICCPR), ń tẹ̀ lé àdéhùn náà, Rọ́ṣíà sì wà lára àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀hún. Ọ̀gbẹ́ni Heiner Bielefeldt tó jẹ́ Aṣojú Pàtàkì fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn tàbí ohun téèyàn gbà gbọ́ sọ pé, “Àwọn tó kọ ohun tó wà nínú àdéhùn ICCPR mọ̀ pé òmìnira ẹ̀sìn tàbí ohun téèyàn gbà gbọ́ ṣe pàtàkì, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ pé àwọn tó fọwọ́ sí àdéhùn náà ò gbọ́dọ̀ yọ kúrò lára rẹ̀ rárá, ìyẹn ni pé wọ́n ò gbọ́dọ̀ bomi là á, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé e délẹ̀délẹ̀, kódà tó bá di ọ̀rọ̀ pàjáwìrì (Àpilẹ̀kọ 4.2). Àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn mélòó kan ló tún fìdí múlẹ̀ bíi tìyẹn, tí wọn ò gbọ́dọ̀ yọ kúrò lára rẹ̀.” Lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ náà ṣe ìpàdé kẹtàléláàádọ́fà (wo àwòrán ìbẹ̀rẹ̀), wọ́n jábọ̀ ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa ohun tí Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe, wọ́n ní tórí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fọwọ́ sí àdéhùn ICCPR, ó lè fẹ́ dà bíi pé wọ́n ń gbèjà ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, àmọ́ ṣe ni àwọn ilé ẹjọ́ tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà ń fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn.

Ọdún 2002 ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe òfin tó dá lórí “Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn” (No. 114-FZ), ọ̀kan lára ohun tó sì mú kí wọ́n ṣe é ni kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ àwọn apániláyà. Àmọ́, wọ́n tún òfin náà ṣe lọ́dún 2006, 2007, àti 2008, tí wọ́n fi wá sọ pé “àwọn apániláyà, tó ń hùwà ipá nìkan kọ́ ni wọ́n ń pè ní agbawèrèmẹ́sìn,” bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Òfin Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Nípa Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn Ta Ko Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn,” tí ìwé ìròyìn The Moscow Times gbé jáde. Ọ̀gbẹ́ni Derek H. Davis, tó jẹ́ ọ̀gá tẹ́lẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ J.M. Dawson Institute of Church-State Studies ní Baylor University sọ pé nínú òfin náà, “kì í ṣe àwọn tó ń hùwà ipá, bí àwọn tó kọ lu Ilé Gogoro Méjì tó wà nílùú New York nìkan ni wọ́n ń pè ní ‘apániláyà,’ apániláyà ni àwọn ẹ̀sìn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò fọwọ́ sí.” Ọ̀gbẹ́ni Davis wá sọ pé “wọ́n ti ṣi òfin yìí lò láti fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà àìtọ́.”

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn kíyè sí i pé ohun tó ń fa wàhálà gan-an ni pé òfin ò ṣàlàyé kedere nípa àwọn tá à ń pè ní agbawèrèmẹ́sìn. Geraldine Fagan, ẹni tó kọ ìwé Believing in Russia—Religious Policy After Communism, ṣàlàyé fún ìwé ìròyìn The Washington Post pé torí pé òfin ò ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà dáadáa, ṣe làwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké kàn ń fìyẹn “rúná sí ọkàn àwọn kan tó pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọn ò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n kọ̀wé sí ìjọba pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Irú ẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n èdè nílùú Vyborg fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì mú kí adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg kéde pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni ìwé ìròyìn méjì tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀gbẹ́ni yìí kan náà tún kọ̀wé pé kí wọ́n kéde pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. March 15, 2016 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ náà.

Àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, tí wọ́n kó sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Central Europe nílùú Selters, orílẹ̀-èdè Germany. Rọ́ṣíà ni wọ́n fẹ́ kó o lọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní March 2015, àwọn agbófinró tó ń rí sí ohun táwọn èèyàn ń kó wọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí í fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó àwọn ìtẹ̀jáde wọn wọlé.

Àwọn ìgbésẹ̀ tó ń jáni láyà tí ìjọba gbé lọ́dún 2015 ló fa ìṣòro táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ní nílé ẹjọ́ lọ́dún 2016. Roman Lunkin, tó jẹ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ Center for Religion and Society Studies ní ilé ẹ̀kọ́ Institute of Europe Russian Academy of Sciences nílùú Moscow sọ pé, “kì í ṣe pé inúnibíni náà le sí i lọ́dún 2015 nìkan ni, ó tún pọ̀ sí i.” Lóṣù March, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó àwọn ìtẹ̀jáde ẹ̀sìn wọn kankan wọ orílẹ̀-èdè náà, títí kan àwọn ìtẹ̀jáde tí àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti ṣàyẹ̀wò tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti sọ pé kì í ṣe ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Lóṣù July, àwọn agbófinró tó ń rí sí ohun táwọn èèyàn ń kó wọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí í fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò gbọdọ̀ kó Bíbélì tí wọ́n ṣe lédè tí wọ́n ń sọ ní Rọ́ṣíà wọ orílẹ̀-èdè. Nígbà tó tún di oṣù July, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòfin de ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jw.org, àwọn nìkan ló sì ṣe irú ẹ̀ lágbàáyé. Lóṣù November, wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó Bíbélì Russian Synodal Bible wọlé. Bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà títí kan Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ló ń lo Bíbélì yìí. Ohun tó wá ṣẹlẹ̀ lópin ọdún yẹn kàmàmà, ìwé ìròyìn The Washington Post pè é ní “ọ̀kan lára ìdájọ́ tó tíì le jù tí ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fáwọn tí wọ́n pè ní agbawèrèmẹ́sìn.” Ṣe ni adájọ́ kan nílùú Taganrog sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlógún (16) jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n hùwà ọ̀daràn torí wọ́n ṣètò láti pàdé pọ̀, tí wọ́n sì ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀.

Àmọ́ ṣe lohun tó ṣẹlẹ̀ ní Taganrog àtàwọn ibòmíì yìí jẹ́ kó dà bíi pé ìjọba ń kó ọ̀rọ̀ ara wọn jẹ. Ọ̀gbẹ́ni Lunkin sọ pé, “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti dàgbà lára àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn lọ́tẹ̀ yìí ní àwọn ìwé ẹ̀rí kan tí ìjọba àtẹ̀yìnwá fún wọn torí wọ́n gbà pé ìjọba ti rẹ́ wọn jẹ sẹ́yìn.” Nígbà ìjọba Soviet Union, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n. Ọdún 1990 ni ìjọba dá ẹni tó kẹ́yìn nínú wọn sílẹ̀. Ìjọba dá àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀ yìí láre, wọ́n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ìwé Ẹ̀rí Ìdáláre tó sọ pé wọn kì í ṣe “ọ̀tá orílẹ̀-èdè,” aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ni wọ́n. Ọ̀gbẹ́ni Lunkin wá sọ pé, “Ṣe ló dà bíi pé kò sóhun tó ń jẹ́ ìdáláre fún wọn mọ́ pẹ̀lú bí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ń gbéjà kò wọ́n yìí pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn.”

Àmọ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ ní May 27, 2015. Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà pa dà fi orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Moscow. March 26, 2004 ni wọ́n ti yọ orúkọ ẹ̀sìn wọn kúrò lábẹ́ òfin nílùú Moscow. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, nígbà tó sì di June 10, 2010, Ilé Ẹjọ́ náà pàṣẹ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pa dà fi orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Moscow, kí wọ́n sì sanwó gbà-máà-bínú fún wọn.

Ní November 11, 2015, Lyubov àti Alexey Koptev, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dì mọ́ra wọn nínú ọgbà wọn nílùú Taganrog, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ní November 30, 2015, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Taganrog sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Koptev àtàwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún míì jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n torí wọ́n ṣètò láti pàdé pọ̀, tí wọ́n sì ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Ọdún méjìdínlógójì (38) ni Ọ̀gbẹ́ni Koptev ti fi ṣiṣẹ́ níléeṣẹ́ ‘Red boilermaker,’ ìyẹn ‘Krasnyy Kotelshik,’ tó ti wà tipẹ́, ìjọba sì gbóríyìn fún un. Ó ti fẹ̀yìn tì, ó sì láwọn ọmọ-ọmọ.

Aṣojú Pàtàkì fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé, “Mo gbà pẹ̀lú àṣẹ tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù pa. Ìgbésẹ̀ tí ìjọba gbé láti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ti ‘le jù,’ wọ́n ‘ṣi òfin lò,’ ìyẹn sì ta ko òmìnira táwọn èèyàn ní láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n.” Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kúkú san owó tí Ilé Ẹjọ́ náà pàṣẹ pé kí wọ́n san, àmọ́ oṣù May ọdún tó kọjá ni wọ́n tó pa dà forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin, lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún márùn-ún tí Ilé Ẹjọ́ náà ti pàṣẹ!

Ìwé Ẹ̀rí Ìdáláre. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nígbà ìjọba Soviet Union torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló gba ìwé ẹ̀rí yìí nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n fi dá wọn láre, wọ́n sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọn kì í ṣe “ọ̀tá orílẹ̀-èdè.”

Agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, Yaroslav Sivulskiy, sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (9,600) ló ń gbé nílùú Moscow báyìí, iye wọn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó dín ẹgbẹ̀rún márùn-ún (175,000) ní gbogbo orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Rọ́ṣíà, títí kan gbogbo àwọn ará wa tó ju mílíọ̀nù mẹ́jọ lọ kárí ayé, ló nírètí pé bí olú-ìlú Rọ́ṣíà ṣe forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin yìí á jẹ́ ká túbọ̀ lómìnira ẹ̀sìn níbi gbogbo lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.” Àmọ́, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n bíi Ọ̀gbẹ́ni Davis sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni láti pa dà forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ṣe ló dà bíi pé ohun tó mú kí wọ́n kí wọ́n ṣe é ni kí wọ́n lè fi mú ẹnu ayé kúrò lára wọn.”

Ọdún mẹ́ta ni Nikolay Trotsyuk (ẹnì kejì láti apá ọ̀tún) fi wà lẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun nígbà ìjọba Soviet Union. Ní November 30, 2015, wọ́n tún fẹ̀sùn kàn án, lọ́tẹ̀ yìí, òun àti Andrey Goncharov àna rẹ̀ (tó wà lápá òsì pátápátá), Oksana Goncharova ọmọ rẹ̀ (ẹnì kẹta láti apá òsì), Sergey Trotsyuk ọmọ rẹ̀ (tó wà lápá ọ̀tún pátápátá) àtàwọn méjìlá (12) míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nílùú Taganrog.

Lọ́dún 2015, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tún ìpinnu tí wọ́n ṣe lọ́dún 2003 àti 2009 sọ pé kí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà “yára ṣàtúnṣe sí Òfin Ìjọba Nípa Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn,” kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí “agbawèrèmẹ́sìn” túmọ̀ sí, kí wọ́n rí i pé àwọn tó hùwà ipá tàbí tí wọ́n ní ìkórìíra ni wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ náà fún, kí wọ́n sì ṣàlàyé tó ṣe kedere nípa àwọn ohun tí wọ́n máa ń kà sí ẹrù àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Bákan náà, Ìgbìmọ̀ náà rọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọ́n “ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó má bàa sí àṣìlò òfin, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe sí àwọn ohun tí ìjọba kà sí Ẹrù Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn.”

Ọ̀gbẹ́ni Lunkin sọ pé, “Ìkórìíra ló ń mú kí wọ́n ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé wọn kì í fìyà jẹ àwọn ẹ̀sìn míì tí wọ́n mọ̀ láwùjọ tí wọ́n ń bá ṣe ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe.” Láìka gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin sí, pẹ̀lú ìsọkúsọ tí wọ́n ń sọ nípa wọn nínú ìròyìn, ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Lunkin parí èrò sí ni pé, “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì wà káàkiri lórílẹ̀-èdè yìí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ń pọ̀ sí i.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, tel. +7 812 702 2691