Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 17, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Bí Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Ṣe Gba Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nílẹ̀ Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Bí Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Ṣe Gba Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nílẹ̀ Rọ́ṣíà

Ní May 3, 2018, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Saint Petersburg máa gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè torí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ọ́fíìsì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bójú tó iṣẹ́ wọn tẹ́lẹ̀ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Bí ìpinnu ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí kò bá gbe àwọn Ẹlẹ́rìí, Ìjọba lè lò ó láti fi gba ilé náà lọ́wọ́ wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Nígbà tí ẹjọ́ náà ń lọ lọ́wọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Sestroretskiy, wọ́n gbójú fo ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ pé àjọ kan tí kì í ṣe torí owó ni wọ́n fi dá a sílẹ̀, ìyẹn Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania (WTPA) tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ló ni ọ́fíìsì náà. Ó ti pé ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ti ilé yìí ti jẹ́ ti àjọ WTPA, tí àjọ náà sì ń sanwó orí lórí rẹ̀ náà. Síbẹ̀, ní December 7, 2017, ilé ẹjọ́ agbègbè náà sọ pé àdéhùn tó wà lórí ilé náà kò bófin mu mọ́. Bí ìpinnu ilé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí kò bá gbe àwọn Ẹlẹ́rìí, lẹ́yìn tí wọ́n bá fi gbogbo ẹsẹ̀ òfin tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tọ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n máa gbé ẹjọ́ náà lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.

Ìgbẹ́jọ́ máa bẹ̀rẹ̀ ní aago mọ́kànlá ààbọ̀ àárọ̀ ní May 3, 2018, ní Ilé Ẹjọ́ Ìlú Saint Petersburg, ul. Basseynaya, 6, St. Petersburg, Rọ́ṣíà.