DECEMBER 27, 2018
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Dẹ́bi fún Arkadya Akopyan Tó Jẹ́ Ẹni Àádọ́rin Ọdún
Ní Thursday, December 27, Adájọ́ Oleg Golovashko ti Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Prohladniy ní Rọ́ṣíà sọ ìpinnu ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Arkadya Akopyan. Ilé ẹjọ́ sọ pé Arákùnrin Akopyan, tó jẹ́ ẹni àádọ́rin (70) ọdún tó ti fẹ̀yìn tì nídìí iṣẹ́ télọ̀, máa fi ọgọ́fà (120) wákàtí ṣe iṣẹ́ ìlú torí ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án pé ó rán àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n lọ máa pín ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn kiri.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò rán Arákùnrin Akopyan lẹ́wọ̀n, ẹjọ́ tí wọ́n dá fún un yìí ta ko ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn. Nítorí náà, a máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé gíga.
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí i, à ń retí ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ máa ṣe lórí ẹjọ́ Arákùnrin Dennis Christensen. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa ti àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà lẹ́yìn, kó sì máa tù wọ́n nínú torí bí wọ́n ṣe ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.