Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 11, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ní Rọ́ṣíà Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Bí Wọ́n Ṣe Fòfin De Bíbélì

Ilé Ẹjọ́ Ní Rọ́ṣíà Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Bí Wọ́n Ṣe Fòfin De Bíbélì

Ní December 6, 2017, ilé ẹjọ́ Leningrad Regional Court gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé wá lórí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré kan dá, pé àwọn fòfin de Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà.

Àwọn lọ́yà kọ́kọ́ ṣàlàyé ìdí tí a kò fi gbà pẹ̀lú ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ Vyborg City Court kọ́kọ́ dá torí ohun tí àwọn tí wọ́n yàn láti ṣèwádìí lórí Bíbélì sọ ni wọ́n fi dájọ́ yẹn. Ilé ẹjọ́ náà kò lè tọ́ka sí apá kan nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó fìdí ẹ̀rí wọn múlẹ̀ pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni. Ilé ẹjọ́ náà ò béèrè fún ẹ̀rí kankan, dípò bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń tẹnu mọ́ ni ohun táwọn tó ṣe ìwádìí yẹn sọ pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun torí pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú rẹ̀, ìyẹn Jèhófà. Àwọn lọ́yà tún rán ilé ẹjọ́ létí pé, tipẹ́-tipẹ́ ni wọ́n ti ń lo orúkọ yẹn ní Rọ́ṣíà, yàtọ̀ síyẹn, orúkọ yẹn tún wà nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì lédè Rọ́ṣíà. Àwọn tó ṣe ìwádìí yẹn tún sọ pé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì torí pé wọn ò kọ ọ́ sí iwájú ẹ̀ pé Bíbélì ni. Kí ilé ẹjọ́ bàa lè mọ̀ pé irọ́ ni ohun tí wọ́n sọ yìí, àwọn lọ́yà wa tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó wà nínú ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó jáde lọ́dún 2007, tó sọ pé: “Bíbélì ìtumọ̀ ayé tuntun lédè Rọ́ṣíà.”

Ilé ẹjọ́ Leningrad Regional Court ti pinnu láti pe àwọn olùwádìí tó máa tún ọ̀rọ̀ yẹn gbé yẹ̀ wò. Ní báyìí, ilé ẹjọ́ ti sún ẹjọ́ náà sí December 20, 2017, aago méjì ààbọ̀ ní ọ̀sán.