Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Yuriy Ivanenko, adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ń kéde pé ilé ẹjọ́ dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà lẹ́bi

APRIL 21, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fòfin De Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fòfin De Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Ní April 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ló ti dá sí ọ̀rọ̀ yìí. Yuriy Grigoryevich Ivanenko, tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, fọwọ́ sí ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ pé kí ìjọba “fòfin de ‘Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà’ àti àwọn ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kí wọ́n sì fa gbogbo ohun ìní wọn . . . lé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ́wọ́.”

Yuriy Ivanenko tó jẹ́ adájọ́ fi kún un pé, ojú ẹsẹ̀ ni ìpinnu yìí máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ìjọba ti fòfin de gbogbo ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láwọn ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ káàkiri Rọ́ṣíà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ṣe báyìí ti fòfin de ìjọsìn wọn.

Àwọn tó ṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà

Vasiliy Kalin wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin nígbà tí àwọn aláṣẹ lé òun àtàwọn òbí rẹ̀ kúrò nílùú lọ sí Siberia torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Ó sọ pé: “Bí ilé ẹjọ́ ṣe dá ẹjọ́ náà lónìí, ó ti nípa tó lágbára lórí ìgbésí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà látòkè délẹ̀, látorí ìdílé-ìdílé dórí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, tí wọ́n bá ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n, kí wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n.”

Philip Brumley, tó jẹ́ Agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ìbànújẹ́ ńlá ni ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe lónìí jẹ́ fún wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, láìgbè sẹ́yìn ẹnì kankan, ẹnikẹ́ni tó bá gbé àwọn ìwé tá a kọ yẹ̀ wò, tó sì gbé àwọn ẹ̀rí tá a mú wá yẹ̀ wò, ibì kan ṣoṣo tó bófin mu tó máa parí èrò sí ni pé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wa ò lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó jẹ mọ́ ti agbawèrèmẹ́sìn. Kò sí tàbí ṣùgbọ́n, a máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.”