Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 18, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Kò Yíhùn Pa Dà Lórí Ẹjọ́ tí Wọ́n Dá Fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tẹ́lẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Kò Yíhùn Pa Dà Lórí Ẹjọ́ tí Wọ́n Dá Fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tẹ́lẹ̀

Ní July 17, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ṣe ohun tó ta ko àdéhùn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe pátápátá, ìyẹn àdéhùn tí wọ́n bá ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé ṣe pé àwọn máa jẹ́ káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé àwọn ò yíhùn pa dà lórí ìpinnu táwọn ti ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn bí wọ́n ṣe sọ pé ìwà ọ̀daràn ni bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ṣe ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Ohun tí ilé ẹjọ́ sọ yìí túmọ̀ sí pé wọ́n ti fòfin de ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Nígbà tí Yuriy Ivanenko tó jẹ́ adájọ́ ilé ẹjọ́ náà dá àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́bi ní April 20, wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn wá yan ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta láti tún ẹjọ́ náà gbọ́, àmọ́ ìgbìmọ̀ náà sọ pé àwọn fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí àwọn Ẹlẹ́rìí pé. Wọ́n sọ pé àwọn ṣì dúró lórí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe lọ́jọ́sí. Nígbà tí ilé ẹjọ́ kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà, ṣe ni adájọ́ fọwọ́ sí ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ pé kí ìjọba “fòfin de ‘Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà’ àti àwọn ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kí wọ́n sì fa gbogbo ohun ìní wọn lé ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ́wọ́.”

Àwọn tó ṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà nílé ẹjọ́

Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, inú ewu làwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́sàn-án [175,000] tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà wà. Philip Brumley, tó jẹ́ Agbẹjọ́rò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà ń ká àwọn ará wọn kárí ayé lára gan-an. Ìpinnu tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ṣe yìí máa jẹ́ káwọn tó ti ń hùwàkiwà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà gbà pé ohun táwọn ṣe bófin mu, á tún jẹ́ káwọn aláṣẹ máa fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n, àwọn èèyàn ò sì ní dáwọ́ ìwàkiwà tí wọ́n ń hù sí wọn dúró. Wọ́n ti wá di ẹni ìtanù gbáà lórílẹ̀-èdè wọn.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ti kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù àti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè, wọ́n ní kí wọ́n báwọn dá ẹjọ́ náà bó ṣe tọ́. Àmọ́ ní báyìí ná, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń gbàdúrà pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún èrò wọn pa lórí ọwọ́ tí wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó tọ́ sí aráàlú, kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa gbé “ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run,” bó ṣe wà nínú 1 Tímótì 2:2.