Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 23, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Tí Ilé Ẹjọ́ Kékeré Kan Dá Pé “Ìwé Agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Tí Ilé Ẹjọ́ Kékeré Kan Dá Pé “Ìwé Agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì

Ní December 6, 2017, ilé ẹjọ́ Leningrad Regional Court máa gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ilé ẹjọ́ kékeré kan dá pé Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Russian kì í ṣe Bíbélì.

Ní August 2017, ilé ẹjọ́ Vyborg City Court gbà pẹ̀lú ohun tí agbẹjọ́rò ìjọba sọ pé, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì torí pé orúkọ Ọlọ́run ìyẹn “Jèhófà” wà nínú ẹ̀. Èyí ló mú kí agbẹjọ́rò ìjọba fi ẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kàn wá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin sọ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé agbawèrèmẹ́sìn, wọn ò sì gbọdọ̀ sọ pé kéèyàn má lò ó.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Russian, a ò sì gbà pẹ̀lú ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ Vyborg City Court dá pé “ìwé agbawèrèmẹ́sì” ni Bíbélì yìí. A ti ṣe Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè mọ́kàn-lé-lọ́gọ́jọ [161], àwọn èèyàn mọyì rẹ̀ gan-an torí ó péye ó sì rọrùn kà. Ìyè ẹ̀dà Bíbélì yìí tá a ti fáwọn èèyàn lé ní ọgọ́rùn-ún méjì [200] mílíọ̀nù.