Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 24, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Sọ Pé Kí Dennis Christensen Ṣì Wà Látìmọ́lé

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Sọ Pé Kí Dennis Christensen Ṣì Wà Látìmọ́lé

Ní July 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Sovietskiy nílùú Oryol sọ pé kí Dennis Christensen ṣì wà látìmọ́lé títí di November 23, 2017. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Ọ̀gbẹ́ni Christensen, ọmọ ilẹ̀ Denmark sì ni. May 25 ni wọ́n mú un, nígbà tí Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò àtàwọn ọlọ́pàá tó fi nǹkan bojú, tí wọ́n sì dira ogun ya wọ ibi tí òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì ti ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nílùú Oryol.

Àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ fún ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn gba béèlì rẹ̀, wọ́n sì ti ṣètò láti san owó tó bá máa ná wọn. Àmọ́ ilé ẹjọ́ ò gbà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí àkọsílẹ̀ kankan pé ó hùwà ọ̀daràn tàbí ìwà ipá ṣáájú àkókò yẹn.

Ní July 17, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Rọ́ṣíà sọ pé àwọn ò yíhùn pa dà lórí ohun tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ sọ, pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kí wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ wọn káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Ẹ̀yìn èyí ni ilé ẹjọ́ wá fi kún ọjọ́ tí Ọ̀gbẹ́ni Christensen máa lò látìmọ́lé. Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá báyìí tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ìjọba mú wọn ní “agbawèrèmẹ́sìn.” Wọ́n ti rí nǹkan hùmọ̀ báyìí láti fi mú àwọn Ẹlẹ́rìí ní ọ̀daràn tí wọ́n bá ń jọ́sìn.

Kate M. Byrnes, Chargé d’Affaires, a.i. of the U.S. Mission to the Organization for Security and Cooperation in Europe, sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ohun tójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí ní Rọ́ṣíà, ó ní: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní July 17 yà wá lẹ́nu, nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dájọ́ pé àwọn ò yíhùn pa dà lórí báwọn ṣe fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, táwọn gbẹ́sẹ̀ lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn àtàwọn ibi márùn-dín-nírínwó [395] tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, lórí ẹ̀sùn pé wọ́n jẹ́ ‘agbawèrèmẹ́sìn.’ Kò ṣeé gbọ́ sétí rárá, pé wọ́n lè mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláàádọ́sàn-án [175,000] lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà báyìí pé ọ̀daràn ni wọ́n torí pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn wọn. Kò múnú ẹni dùn rárá bí àwọn aláṣẹ ṣe ń ṣi òfin ‘agbawèrèmẹ́sìn’ lò láti fìyà tí kò tọ́ jẹ àwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké tí wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn wọn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.”