Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 23, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Sọ Pé Kí Dennis Christensen Ṣì Wà Látìmọ́lé

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Sọ Pé Kí Dennis Christensen Ṣì Wà Látìmọ́lé

Ní February 22, 2018, Aleksey Rudnev, tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy nílùú Oryol, sọ pé kí Dennis Christensen ṣì wà látìmọ́lé di August 1, 2018. Torí pé Ọ̀gbẹ́ni Christensen ṣètò ìjọsìn lórúkọ ẹ̀sìn tí ìjọba ti sọ pé ó jẹ́ tàwọn agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n ṣe pè é lẹ́jọ́. Kódà, ibi tó ti ń ṣèpàdé ẹ̀sìn Kristẹni ló wà táwọn ọlọ́pàá fi ya wọ ibẹ̀, tí wọ́n sì mú un ní May 2017.

February 19 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Lọ́jọ́ yẹn, adájọ́ ò gba ìkankan nínú ohun tí olùjẹ́jọ́ àti olùpẹ̀jọ́ sọ wọlé. Àmọ́ nígbà tó di February 22, ṣe ni adájọ́ fagi lé gbogbo ohun tí àwọn agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Christensen sọ, ó wá sọ pé kó ṣì wà látìmọ́lé. Wọ́n máa pa dà bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án ní February 26, ní aago méjì ààbọ̀ ọ̀sán.

Ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Christensen ń ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lára, àdúrà wọn sì ni pé kí Irina ìyàwó rẹ̀ lè máa fara dà á láìsí àtìlẹ́yìn ọkọ rẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Christensen ti lo oṣù mẹ́sàn-án látìmọ́lé báyìí.