Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 16, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Fẹ́ Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Fẹ́ Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti gbé ẹjọ́ kan wá sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ pé “kí wọ́n kéde pé agbawèrèmẹ́sìn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé iṣẹ́ yìí ni wọ́n ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn, kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì ti ọ́fíìsì náà pa.” Ní March 15, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kọ ọ́ sórí ìkànnì wọn pé Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ló gbé ẹjọ́ yìí wá. Ilé Ẹjọ́ náà wá pa dà fi tó Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà létí pé àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, wọ́n sì ti ṣètò pé wọ́n á gbọ́ ẹjọ́ náà ní April 5, 2017, ní aago mẹ́wàá àárọ̀.

Tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ bá dá Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ láre lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó máa ṣàkóbá gan-an fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà. Ìjọba lè gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò fún ìjọsìn, wọ́n lè fòfin de ibi ìjọsìn wọn tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] tí wọ́n ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n sì lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́sàn-án [170,000] tó wà lórílẹ̀-èdè náà torí pé wọ́n ń pàdé pọ̀ láti jọ́sìn, láti jọ ka Bíbélì tàbí tí wọ́n bá ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì.

Vasiliy Kalin, tó jẹ́ aṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà sọ pé: “Ohun tó jà jù lọ́kàn gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà ni pé ká ṣáà lè máa sin Ọlọ́run wa láìsí ìyọlẹ́nu. Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún báyìí tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ń tẹ àwọn òfin táwọn fúnra wọn ṣe lójú, bẹ́ẹ̀ àwọn òfin ọ̀hún gbà wá láyè láti ṣe ẹ̀sìn wa. Ọmọdé lásán ni mí nígbà tí Stalin tó jẹ́ aláṣẹ nígbà yẹn fi lé ìdílé wa kúrò nílùú lọ sí Siberia. Torí kí sì ni? Kò ju torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Inú mi ò dùn rárá pé ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ mi àtàwọn ọmọ-ọmọ mi báyìí, kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Níbi táyé lajú dé yìí, mi ò rò ó rí pé wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa ṣenúnibíni sí wa lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní Rọ́ṣíà.”