Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọrin nínú ìpàdé kan tí wọ́n ń ṣe nílùú Rostov-on-Don, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

SEPTEMBER 22, 2016
RỌ́ṢÍÀ

APÁ KÌÍNÍ

Ohun Táwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Sọ: Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ń Lọ́ Òfin Agbawèrèmẹ́sìn Po Kí Wọ́n Lè Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ohun Táwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Sọ: Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ń Lọ́ Òfin Agbawèrèmẹ́sìn Po Kí Wọ́n Lè Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Apá Kìíní nìyí nínú àpilẹ̀kọ alápá mẹ́ta tó dá lórí ohun táwọn gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn, ohun tó ń lọ láwùjọ àti òṣèlú tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ àti ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n míì sọ, ìyẹn àwọn tó mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé ìjọba Soviet àti lẹ́yìn tí wọ́n kógbá wọlé.

ÌLÚ ST. PETERSBURG, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà—Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fẹ́ kí wọ́n kéde pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tí ilé ẹjọ́ bá dá wọn láre, èyí lè mú kí wọ́n ti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà pa, kí wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ wọn káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, a sì ń retí pé ìgbẹ́jọ́ náà máa pa dà bẹ̀rẹ̀ ní September 23, 2016.

Òfin agbawèrèmẹ́sìn tí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ló fà á tí wọ́n fi pe àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́jọ́. Ṣe ni àwọn ọ̀mọ̀wé ń sọ pé ìjọba ń fi òfin náà “ṣe ẹ̀tanú,” pé “àṣìṣe kún inú rẹ̀,” wọ́n tún ń sọ pé “ó ṣe kedere pé òfin náà ò bá tayé mu.”

Dr. Derek H. Davis

Dr. Derek H. Davis, tó jẹ́ ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ J.M. Dawson Institute of Church-State Studies tẹ́lẹ̀ ní Baylor University, sọ pé: “Àwọn agbawèrèmẹ́sìn tó ń wu ẹ̀mí àwọn èèyàn léwu ló yẹ kí wọ́n máa gbéjà kò. Tó bá jẹ́ àwọn tí ò wu ẹ̀mí ẹlòmíì léwu lèèyàn ń yọ lẹ́nu, agbawèrèmẹ́sìn lonítọ̀hún fúnra ẹ̀.”

Dr. Mark Juergensmeyer

Dr. Mark Juergensmeyer, tó jẹ́ ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ Orfalea Center for Global and International Studies ní University of California nílùú Santa Barbara ṣàlàyé ohun tó fà á tí wọ́n fi ń fínná mọ́ àwọn ẹlẹ́sìn àlàáfíà bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ní: “Ọgbọ́nkọ́gbọ́n ni wọ́n ń ta bí wọ́n ṣe ń fi òfin agbawèrèmẹ́sìn ṣèdíwọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n má bàa lómìnira ẹ̀sìn, ohun burúkú gbáà sì nìyẹn.” Dr. Jim Beckford, tó wà nínú àjọ British Academy náà fi kún un pé, “Ṣe ni àwọn ará Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ìjọba kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́, kí wọ́n sì lè gbá ẹ̀sìn èyíkéyìí tí wọ́n bá wò pé ó ń bá àwọn figa gbága wọlẹ̀.”

Dr. Jim Beckford

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé kì í ṣe bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣi òfin lò nìkan ni ìṣòro, àmọ́ bí àwọn tó ṣòfin ọ̀hún pàápàá ṣe ṣe é ń mú káwọn èèyàn máa ṣì í lò. Àjọ SOVA Center for human rights tó wà ní Moscow sọ pé: “Kì í ṣòní, kì í ṣàná la ti ń sọ ọ́ pé ọ̀rọ̀ inú òfin agbawèrèmẹ́sìn tí wọ́n ṣe yẹn ò ṣe kedere, àwọn èèyàn sì lè ṣì í lò, kí wọ́n fi ta ko àwọn olóṣèlú tí ò bá gba tiwọn tàbí àwọn míì tí wọ́n dá yàtọ̀ láwùjọ.”

Dr. Emily B. Baran

Dr. Emily B. Baran, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ní ẹ̀ka Russian and Eastern European history ní Middle Tennessee State University sọ pé: “Kò yẹ káwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ bí ìjọba ṣe ń ṣe ẹ̀tanú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí, torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun kan náà ni wọ́n máa ṣe sáwọn míì àtàwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké tó kù, tí wọ́n á máa fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, 7-812-702-2691