Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 29, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn ọlọ́pàá Rọ́ṣíà lọ kó àwọn tó ń ṣe ìjọsìn, wọ́n sì ti ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark mọ́lé

Àwọn ọlọ́pàá Rọ́ṣíà lọ kó àwọn tó ń ṣe ìjọsìn, wọ́n sì ti ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark mọ́lé

Ní May 25, 2017, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn àjọ aláàbò tí wọ́n ń pè ní Federal Security Service (FSB) lọ dí àwọn ará wa lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nílùú Oryol lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àwọn aláṣẹ fẹ̀sùn kàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé à ń kóra jọ gẹ́gẹ́ bí àjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Ní June 14, 2016, ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn nílùú Oryol lórí ẹ̀sùn pé agbawèrèmẹ́sìn ni wá. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún gba àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa àwọn ará tó wà nípàdé lọ́jọ́ yẹn, wọ́n gba àwọn fóònù àti tablet wọn, wọ́n sì tún lọ yẹ ilé wọn wò bóyá wọ́n á rí àwọn nǹkan míì.

Àwọn aláṣẹ yìí tún kó àwọn arákùnrin inú ijọ tó wà ní Oryol lọ sí ọ́fíìsì àjọ aláàbò tí wọ́n ń pè ní FSB, wọ́n sì tún fi ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ yẹn sẹ́wọ̀n, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dennis Christensen tó wá láti orílẹ̀-èdè Denmark. Wọ́n tún sọ pé kí Ilé Ẹjọ́ àgbègbè Sovietskiy fi ọ̀gbẹ́ni Christensen sí àtìmọ́lé tí ẹnikẹ́ni ò ní lè gbà á sílẹ̀, èyí á lè fún àwọn òṣìṣẹ́ ààbò yẹn láyè láti wá àwọn ẹ̀rí tí wọ́n á fi ṣe ẹjọ́ wa. Adájọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Svetlana Naumova ló fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ti ọ̀gbẹ́ni Christensen mọ́lé fún oṣù méjì. Wọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́ lónìí. Tó bá jẹ̀bi, ó ṣeé ṣe kó ṣẹ̀wọn ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé òfin sọ nínú Article 282.2 apá kìíní.

Àwùjọ àwọn èèyàn tó kó ara wọn jọ láti jọ́sìn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Oryol, wọn kì í ṣe àjọ tí wọ́n fi òfin gbé kalẹ̀. Ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe yìí fi hàn pé ìjọsìn wa ni wọ́n fẹ́ dá dúró kì í ṣe àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará wa tó wà ní Taganrog, ìjọba kọ́kọ́ gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn, wọ́n tún wá fẹ̀sùn kan àwọn ará mẹ́rìndínlógún torí wọ́n ń jọ́sìn, wọ́n sọ pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Ní November 2015, wọ́n sọ nílé ẹjọ́ pé àwọn ará mẹ́rìndínlógún yẹn jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, àmọ́ wọ́n sọ ìdájọ́ wọn di ìgbà míì. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ń tún ẹjọ́ wọn gbé yẹ̀ wò lọ́wọ́.