MAY 10, 2018
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Gbọ́ Tẹnu Àwọn Ẹlẹ́rìí Fúngbà Àkọ́kọ́ Níbi Ìgbẹ́jọ́ Dennis Christensen
Ní April 23, 2018, ìgbẹ́jọ́ Dennis Christensen pa dà bẹ̀rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy nílùú Oryol. Ọmọ ilẹ̀ Denmark ni Ọ̀gbẹ́ni Christensen, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Ibi ìpàdé kan tí wọ́n ti ń ṣèjọsìn ló wà ní May 2017 tí wọ́n fi mú un, àtìgbà yẹn ló sì ti wà látìmọ́lé.
Ọ̀gbẹ́ni Fomin tó jẹ́ olùpẹ̀jọ́ fẹ̀sùn kan Ọ̀gbẹ́ni Christensen pé ó ń ‘ṣètò iṣẹ́ fún iléeṣẹ́ kan tó jẹ́ ti àwọn agbawèrèmẹ́sìn,’ ìyẹn àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Oryol, èyí tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ní June 2016 lórí ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n fi kàn wọ́n pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Àwọn agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Christensen sọ pé àwọn ò fara mọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án torí pé òfin ò de ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Oryol, èèyàn àlàáfíà tó ń kóra jọ láti jọ́sìn, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n. Àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ tẹnu mọ́ ọn pé àwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà fúnra wọn gbà pé ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ làwọn fòfin dè, àti pé òfin ilẹ̀ Rọ́ṣíà fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tó bá gbà gbọ́. * Torí náà, nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Christensen ń ṣèjọsìn níbi tí wọ́n ti rí i, ohun tó gbà gbọ́ ló ń ṣe.
April 24, 2018 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ tẹnu àwọn ẹlẹ́rìí. Olùpẹ̀jọ́ kọ́kọ́ ké sí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan tó ń bá àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba Àpapọ̀ ṣiṣẹ́ pé kó wá sọ tẹnu ẹ̀. Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà jẹ́rìí sí i pé àtọdún 2017 lòun ti ń fi kámẹ́rà ká ohun tó ń lọ láyìíká Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Oryol. Àmọ́ kò lè ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ilé, torí ohun tí wọ́n rí nínú kámẹ́rà ò ju bí Ọ̀gbẹ́ni Christensen ṣe ń kí àwọn yòókù tọ̀yàyà-tọ̀yàyà nígbà tí wọ́n ń wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Olùpẹ̀jọ́ náà wá ké sí obìnrin kan tó ń gbé nílùú yẹn tó ti lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ní Oryol. Àmọ́ kò rí nǹkan sọ nípa ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Christensen ń ṣe torí pé kí ìjọba tó gbẹ́sẹ̀ lé àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Oryol ló ti lọ sípàdé náà gbẹ̀yìn.
Lọ́jọ́ kejì, olùpẹ̀jọ́ ké sí obìnrin ọlọ́dún méjìdínlọ́gọ́rin (78) kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó wá sọ tẹnu ẹ̀. Lẹ́yìn tí olùpẹ̀jọ́ náà bi í lóríṣiríṣi ìbéèrè fún wákàtí méjì àtààbọ̀ torí kó lè rí “ẹ̀rí” tó máa fi kó bá Ọ̀gbẹ́ni Christensen, ohun tí obìnrin náà sọ ò ju pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lọ́gàá, wọn ò sì ní olórí, àti pé tí wọ́n bá ń ṣèpàdé lọ́wọ́, wọn kì í lo àwọn ìwé ẹ̀sìn tí ìjọba Rọ́ṣíà ti fòfin dè.
Ìgbẹ́jọ́ náà máa pa dà bẹ̀rẹ̀ ní May 14, 2018, wọ́n sì ti ṣètò pé á máa lọ bẹ́ẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan nínú oṣù yẹn. Tí wọ́n bá sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Christensen jẹ̀bi, wọ́n lè ní kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá gbára. Ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ yìí ti kó ìdààmú ọkàn bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Christensen àti Irina ìyàwó ẹ̀ sì ń ká wọn lára.
^ ìpínrọ̀ 3 Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fọwọ́ sí i pé kí ìjọba fòfin de àjọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Oryol, ohun tí wọ́n sọ nígbà náà ni pé: “A ò ní fi ẹ̀tọ́ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn náà dù wọ́n pé kí wọ́n má sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́, torí pé ìjọba ò ní kí wọ́n má kóra jọ láti ṣe ìsìn, tí kò bá ṣáà ti ní ín ṣe pẹ̀lú pípín àwọn ìwé ẹ̀sìn tó jẹ́ ti agbawèrèmẹ́sìn.”