JULY 14, 2016
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Pè Nípa Àwọn Tó Ń Halẹ̀ Pé Àwọn Máa Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn ní Rọ́ṣíà Pa
Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Tver nílùú Moscow fọwọ́ sí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí pè torí lẹ́tà tí Agbẹjọ́rò Àgbà kọ láti fi kìlọ̀ fún wọn pé àwọn máa ti ọ́fíìsì wọn lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pa. Ilé ẹjọ́ náà máa gbọ́ ẹjọ́ yìí ní July 18, 2016, wọ́n á pinnu bóyá ohun tí Agbẹjọ́rò Àgbà sọ yẹn bófin mu.
Yàtọ̀ sí ohun tí Agbẹjọ́rò yìí ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí fà ní Rọ́ṣíà, àwọn kan tún ń pitú tiwọn lọ́tọ̀. Àwọn mẹ́ńbà Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìlú Arkhangelsk kọ̀wé sí Ọ̀gbẹ́ni Aleksandr Konovalov, tó jẹ́ Mínísítà Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹjọ́. Wọ́n kọ̀wé pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣòfin láti fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ohun tí òfin fọwọ́ sí tó jẹ́ tiwọn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.