Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 29, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́síà Kéde Pé Ìwé “Agbawèrèmẹ́sìn” Ni Bíbélì

Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́síà Kéde Pé Ìwé “Agbawèrèmẹ́sìn” Ni Bíbélì

Ní August 17, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg kéde pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde ní ọ̀pọ̀ èdè. * Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí wọ́n máa fòfin de Bíbélì ní orílẹ̀-èdè tí ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ọmọ ibẹ̀ ti ń sọ pé Kristẹni làwọn.

Lápa ìparí oṣù July 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg pa dà bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n ti sún síwájú láti April 2016 torí pé kí àwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n lè ráyè ṣàyẹ̀wò lórí Bíbélì náà. Àwọn aláṣẹ ìrìnnà Leningrad-Finlyandskiy Transport ló pe ẹjọ́, tí wọ́n sì sọ fún ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n yan àwọn “ọ̀jọ̀gbọ́n” tó máa ṣàyẹ̀wò Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun láti mọ̀ bóyá ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni, ilé ẹjọ́ sì fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ àkókò falẹ̀, àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò parí àyẹ̀wò wọn, wọ́n sì gbé e lọ síwájú ilé ẹjọ́ ní June 22, 2017. Ibi tí wọ́n parí àyẹ̀wò ọ̀hún sí ni pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì náà. Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí ò yàtọ̀ sí ìpinnu táwọn ilé ẹjọ́ míì ti ṣe tẹ́lẹ̀, láwọn ìgbà tí wọ́n ní kí àwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ṣe irú àyẹ̀wò yẹn lórí àwon ìwé míì tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn Ni Wọ́n Gbé Àyẹ̀wò Náà Kà, Kì Í Ṣe Orí Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́

Kí àwọn tó ṣe àyẹ̀wò náà lè kín ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn, wọ́n ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun “kì í ṣe Bíbélì.” Ohun tí wọ́n sọ yìí mú kéèyàn má lè fi Òfin Tó Dá Lórí Gbígbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, èyí tó sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ pe àwọn ìwé mímọ́ bíi Bíbélì ní ìwé agbawèrèmẹ́sìn mú wọn. Yaroslav Sivulskiy, tó jẹ́ aṣojú Ẹgbẹ́ Àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù, sọ pé: “Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣi òfin agbawèrèmẹ́sìn lò lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn wa. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọn dọ́gbọ́n sí i kí òfin má bàá mú wọn. Ọgbọ́n tí wọ́n sì dá ni bí wọn ṣe sọ pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì torí kí wọ́n lè kéde pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni. Ṣe lọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ohun táwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ò ní ṣe kí wọ́n lè ba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́.”

“A ò lè pe Bíbélì, Koran, Tanakh àti Kangyur, títí kan àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí àtàwọn ọ̀rọ̀ tá a fà yọ nínú wọn ní ìwé àwọn agbawèrèmẹ́sìn.”—Àtúnṣe sí Òfin Orílẹ̀-èdè Rọ́síà Tó Dá Lórí Gbígbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, Àpilẹ̀kọ 3.1: Àwọn ìgbésẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó bá kan lílo òfin Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tó dá lórí gbígbéjà ko àwọn agbawèrèmẹ́sìn lórí ọ̀rọ̀ àwọn ìwé ẹ̀sìn.

Ohun táwọn tó ṣe àyẹ̀wò gbé ọ̀rọ̀ wọn kà gangan láti fi ti ohun tí wọ́n sọ lẹ́yìn pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun “kì í ṣe Bíbélì” ni pé, wọ́n ní “Jèhófà” ló pe orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n lo lẹ́tà mẹ́rin * fún lédè Hébérù. Àwọn agbẹjọ́rò tó ń ṣojú fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ẹ̀rí wá láti fi hàn pé èrò àwọn tó ṣe àyẹ̀wò náà kò tọ́. Àwọn agbẹjọ́rọ̀ náà fi àwọn Bíbélì èdè Rọ́ṣíà mẹ́wàá míì tó lo orúkọ náà Jèhófà han ilé ẹjọ, wọ́n tún fi àwọn ìwé ewì tí Tsvetaeva àti Pushkin kọ, títí kan àwọn ìwé tí Kuprin, Goncharov àti Dostoyevsky kọ, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ míì tí wọ́n fà yọ látinú àwọn ìwé pàtàkì lédè Rọ́ṣíà. Wọ́n tún tọ́ka sí Bíbélì Makarios, ìyẹn Bíbélì èdè Rọ́ṣíà tí wọ́n ṣe jáde láàárín ọdún 1800 sí 1899. Àwọn atúmọ̀ èdè tó jẹ́ oníṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló túmọ̀ rẹ̀, orúkọ náà Jèhófà sì fara hàn níbẹ̀ ní ìgbà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3500].

Bákan náà, ilé ẹjọ́ gba àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n méjì láyè láti sọ tẹnu wọn, kí wọ́n fi hàn pé Bíbélì Mímọ́ ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lóòótọ́. Níbi ìgbẹ́jọ́ yẹn ní August 9, Ọ̀jọ̀gbọ́n Anatoliy Baranov, * tó jẹ́ onímọ̀ nípa èdè táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún, jẹ́rìí sí i pé bí àwọn gbólóhùn tó wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe yàtọ̀ sí ti Bíbélì tí wọ́n ń lò ní ṣọ́ọ̀ṣì ò túmọ̀ sí pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì. Kò sí bí ìtumọ̀ Bíbélì méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe lè lo ọ̀rọ̀ kan náà. Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá Bíbélì kan tí wọ́n ṣe jáde lóde òní péye lóòótọ́, àfi ká fi wéra pẹ̀lú Bíbélì tí wọ́n kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ (lédè Hébérù, Árámáìkì tàbí Gíríìkì) dípò ká fi wé èyí tó jẹ́ pé irú èdè yẹn náà ni wọ́n fi kọ ọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ díẹ̀ tí wọ́n ti kọ ọ́.

Níbi ìgbẹ́jọ́ yẹn ní August 16, Mikhail Odintsov, * tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nípa ẹ̀sìn jẹ́rìí sí i pé kókó ọ̀rọ̀ inú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ò yàtọ̀ sí tàwọn Bíbélì èdè Rọ́ṣíà yòókù, bí wọ́n sì ṣe to àwọn ìwé inú rẹ̀ bá ti àwọn Bíbélì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò mu. Ọ̀gbẹ́ni Odintsov sọ̀rọ̀ lórí bí Bíbélì náà ṣe lo orúkọ Ọlọ́run, ó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé “Jèhófà” làwọn atúmọ̀ èdè míì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà lò, títí kan àwọn tó túmọ̀ Bíbélì táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń lò, nǹkan bí ìgbà mẹ́wàá ni Bíbélì yìí tiẹ̀ lo orúkọ náà.

Àwọn tó ṣe àyẹ̀wò tún sọ pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì torí pé wọn ò kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé Bíbélì ni. Àmọ́, Ọ̀gbẹ́ni Odintsov ṣàlàyé pé ó tọ́ láti pe Bíbélì ní “Ìwé Mímọ́.”

Ìgbẹ́jọ́ Lórí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun—Ọ̀nà Míì Tí Wọ́n Fẹ́ Fi Rẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Jẹ

Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg ṣe ò tíì múlẹ̀, ìjọba ò sì tíì fi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kún àwọn ìwé tí wọ́n kà sí Ìwé Agbawèrèmẹ́sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Leningrad láàárín ọgbọ̀n [30] ọjọ́ láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tí ìjọba ti ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, àmọ́ èyí tí wọ́n ṣe yìí, tí wọ́n sọ pé àwọn máa fòfin de Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí fi ń jọ́sìn ló wà lójú ọpọ́n báyìí. July 17 lọ̀rọ̀ dójú ẹ̀, nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ pé àwọn ò yíhùn pa dà lórí ohun táwọn ti sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ọ̀daràn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Rọ́ṣíà. Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg wá ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìjọba Rọ́ṣíà ò jáwọ́ nínú inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìtọ́.

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀ Ẹjọ́ Táwọn Aláṣẹ Pè Lórí Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

  1. August 17, 2017

    Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg gbà pẹ̀lú ohun tí olùpẹ̀jọ́ sọ pé kí wọ́n kéde pé “ìwé agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

  2. August 9, 2017

    Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg pa dà bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ àyẹ̀wò Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

  3. June 6, 2017

    Ìròyìn látọ̀dọ̀ iléeṣẹ́ Center of Sociocultural Expert Studies fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun “kì í ṣe Bíbélì” àti pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni

  4. December 23, 2016

    Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fọwọ́ sí ẹjọ́ táwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké ti dá tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo Bíbélì tí wọ́n gbà ní July 2015

  5. April 26, 2016

    Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg pàṣẹ pé kí iléeṣẹ́ Center of Sociocultural Expert Studies bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò lórí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kí wọ́n lè rí àmì èyíkéyìí tó bá fi hàn pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni

  6. March 15, 2016

    Torí ohun tí olùpẹ̀jọ́ sọ, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ kí wọ́n lè kéde pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

  7. December 29, 2015

    Ilé ẹjọ́ Arbitration Court ti ìlú St. Petersburg àti Àgbègbè Leningrad ò gba ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ lórí ọ̀rọ̀ àwọn Bíbélì wọn táwọn aláṣẹ gbà láìtọ́

  8. August 13, 2015

    Àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ohun tó ń wọ̀lú, tó sì ń jáde nílùú Vyborg gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo Bíbélì tí iye wọn jẹ́ 2,016 tó wà nínú ẹrù tó wọlé sí orílẹ̀-èdè náà ní July 13, wọ́n ní ó ṣeé ṣe káwọn rí ẹ̀rí nínú ẹ̀ pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni

  9. July 14, 2015

    Àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ohun tó ń wọ̀lú, tó sì ń jáde nílùú Vyborg gba ẹ̀dà Bíbélì mẹ́ta, wọ́n láwọn fẹ́ fún àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀ kó lè hàn pé ó tọ́ báwọn ṣe gbà á

  10. July 13, 2015

    Àwọn aláṣẹ tó ń rí sí ohun tó ń wọ̀lú, tó sì ń jáde nílùú Vyborg ò jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ẹrù wọ̀lú, bẹ́ẹ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà nìkan ló wà nínú ẹrù náà

^ ìpínrọ̀ 2 A ti tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó lé ní ọgọ́fà [120]. Ẹ̀dà tá a ti pín ti lé ní mílíọ̀nù lọ́nà igba.

^ ìpínrọ̀ 6 Lẹ́tà mẹ́rin yìí, יהוה, ni wọ́n ń lò fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù. Lédè Gẹ̀ẹ́sì, ohun táwọn lẹ́tà náà túmọ̀ sí ni YHWH tàbí JHVH. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà tó fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (táwọn èèyàn máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé).

^ ìpínrọ̀ 7 Professor Baranov wà nínú ìgbìmọ̀ Expert Committee for Certifying Expert Linguists at the Russian Center for Judicial Expert Studies, òun sì ni ọ̀gá ní ẹ̀ka Department of Experimental Lexicography of the Institute of the Russian Language of the Russian Academy of Sciences.

^ ìpínrọ̀ 8 Ògbógi ni Professor Odintsov, ó sì wà nínú àjọ Academic Council of the Russian State Archive of Socio-Political History, òun tún ni ààrẹ ẹgbẹ́ Association of Researchers of Religion.