Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ibi tí wọ́n ti já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

MAY 2, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣúkaṣùka Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Wọ́n Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣúkaṣùka Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Káàkiri orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó ti tó ìlú méje báyìí, ó kéré tán tí wọ́n ti ń fipá já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó jọ pé ṣe ni wọ́n dìídì ṣètò àwọn ọlọ́pàá kan tó dá yàtọ̀ (OMON), tí wọ́n máa ń da nǹkan bojú tí wọ́n sì máa ń gbé ìbọn arọ̀jò ọta bí wọ́n ṣe ń já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n á na ìbọn sí wọn, tí wọ́n á sì dá tọmọdé tàgbà jókòó láti máa da ìbéèrè bò wọ́n.

Arkadya Akopyan, àti ìyàwó rẹ̀, Sonya, àtàwọn ọmọ-ọmọ wọn obìnrin méjì

Lọ́dún tó kọjá, ó kéré tán, àwọn aláṣẹ ti fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn mẹ́wàá kan àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì ju àwọn márùn-ún sẹ́wọ̀n, títí kan Dennis Christensen, tó ti wà látìmọ́lé láti May 25, 2017 láìtíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n ń ṣẹjọ́ Arkadya Akopyan, Ẹlẹ́rìí míì tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin (69) ní Republic of Kabardino-Balkaria. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ju gbogbo wọn sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì sí mẹ́wàá torí pé wọ́n pé jọ láti jọ́sìn.

Ní April 20, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà fi òfin de Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti gbogbo àjọ márùn-dín-nírínwó (395) tí àwa Ẹlẹ́rìí fòfin gbé kalẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ ń lọ lọ́wọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun fi òpin sí àwọn àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi òfin gbé kalẹ̀, Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ṣì lè máa ṣe ìsìn rẹ̀ nìṣó. Àmọ́, ohun tí ìjọba ń ṣe yàtọ̀ sí ohun tó sọ.

Ní báyìí táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti fòpin sí àwọn àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin, tí wọ́n sì ti ń gba àwọn dúkìá tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n tún ti dájú sọ àwọn èèyàn yìí àti ìjọsìn wọn. Wọ́n ti wá kà á sí ìwà ọ̀daràn báyìí tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-dín-lọ́gọ́sàn-án (175,000) lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bá ń ṣe ẹ̀sìn wọn.

Wọ́n Já Wọlé Àwọn Ẹlẹ́rìí, Wọ́n Da Ìbéèrè Bò Wọ́n, Wọ́n Tì Wọ́n Mọ́lé

Láti oṣù January ọdún 2018 ni àwọn agbófinró ti dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀rọ̀ náà sì ti wá ń di lemọ́lemọ́.

April 20, 2018, Shuya, Agbègbè Ivanovo: Àwọn agbófinró yẹ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin wò. Àwọn agbófinró náà mú Dmitriy Mikhailov lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n tì í mọ́lé, wọ́n sì fi í sílẹ̀ lẹ́yìn náà. Àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìwà ọ̀daràn lórí rẹ̀ wọ́n sì sọ pé ó ti tàpá sí Abala kejìlélọ́gọ́rin-lé-nígba (282), ìsọ̀rí kejì, apá kejì nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn torí pé ó ‘ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.’ Wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ jáde nínú ìlú Shuya títí dìgbà tí wọ́n bá tó sọ pé ó lè ṣe bẹ́ẹ̀.

April 19, 2018, Vladivostok: Àwọn ọlọ́pàá àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò (FSB) já wọnú ilé elérò-púpọ̀ kan, wọ́n sì mú Valentin Osadchuk àtàwọn obìnrin àgbàlagbà mẹ́ta lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn. Àwọn aláṣẹ sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Osadchuk ti tàpá sí Abala kejìlélọ́gọ́rin-lé-nígba (282), ìsọ̀rí kejì, apá kejì nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn, ìyà rẹ̀ ni ẹ̀wọ̀n ọdún méjì sí mẹ́rin, wọ́n sì tì í mọ́lé láìtíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ní April 23, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Frunzenskiy pàṣẹ pé kí Ọ̀gbẹ́ni Osadchuk wà látìmọ́lé títí di June 20, 2018, kí ìgbẹ́jọ́ tó wáyé. Ó ṣì wà látìmọ́lé ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìwádìí Àkọ́kọ́ ní Vladivostok.

April 18, 2018, Polyarny, Agbègbè Murmansk: Ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọlọ́pàá míì tó dá yàtọ̀ (OMON) tí wọ́n dá nǹkan bojú tí wọ́n sì gbé ìbọn arọ̀jò ọta jálẹ̀kùn wọnú ilé Roman Markin. Wọ́n na ìbọn sí i pé kó dojú bolẹ̀. Nígbà tí ọmọbìnrin rẹ̀ tí kò tíì pé ogún ọdún rí àwọn ọlọ́pàá tó dira ogun náà, kíá ló dùbúlẹ̀ tó sì ká ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí. Àwọn ọlọ́pàá yẹ gbogbo àyíká ilé náà wò, lẹ́yìn náà wọ́n mú Ọgbẹ́ni Markin lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n sì tì í mọ́lé títí á fi fojú ba ilé ẹjọ́.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn náà, àwọn ọlọ́pàá yẹ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlá (14) míì wò ní agbègbè yẹn, wọ́n sì gba fóònù alágbèéká, tablet àtàwọn ohun nǹkan wọn míì. Lẹ́yìn náà, àwọn ọlọ́pàá mú àwọn Ẹlẹ́rìí náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn. Àwọn aláṣẹ agbègbè náà fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Ọ̀gbẹ́ni Markin àti Ẹlẹ́rìí míì ládùúgbò ibẹ̀, ìyẹn Viktor Trofimov. Wọ́n sọ pé àwọn méjèèjì tàpá sí Abala kejìlélọ́gọ́rin-lé-nígba (282), ìsọ̀rí kejì, apá kìíní nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn torí pé wọ́n ‘ń bá àjọ agbawèrèmẹ́sìn kan ṣètò iṣẹ́ rẹ̀.’ Bí ilé ẹjọ́ bá sọ pé wọ́n jẹ̀bi, wọ́n lè ran wọn lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá. Àwọn méjèèjì wà látìmọ́lé báyìí ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Àkọ́kọ́ ní Agbègbè Murmansk títí wọ́n a fi gbọ́ ẹjọ́ wọn.

April 10, 2018, Zaton Agbègbè Ufa: Láàárín aago mẹ́fà ààbọ̀ sí aago méje àárọ̀, àwọn tó ń ṣèwádìí àtàwọn ọlọ́pàá kan tó dá yàtọ̀ (OMON) já wọlé àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan wọ́n sì yẹ ilé wọn wò. Bí èyí ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni àwọn ọlọ́pàá náà ń da ìbéèrè bo àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Níbì kan, ọlọ́pàá sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé: “A máa fi ẹ́ sílẹ̀ gbàrà tó o bá ti sọ pé o kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.” Níbòmíì, ọlọ́pàá kan sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé: “Gbogbo yín pátá la máa yanjú kúrò láyé.” Wọ́n kó gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kí wọ́n lè tẹ̀ka, kí wọ́n sì túbọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn.

Nígbà táwọn ọlọ́pàá já wọlé Ọ̀gbẹ́ni Khafizov àtìyàwó rẹ̀, wọ́n na ìbọn sí tọkọtaya náà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yẹ gbogbo àyíká ilé wọn wò. Lẹ́yìn tí wọ́n yẹ ilé wọn wò tán, ọlọ́pàá kan he ìyàwó Khafizova lápá, ó tì í wọnú ọkọ̀ ọlọ́pàá, ó sì mú un lọ sí àgọ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Khafizov kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Anatoliy àti Alyona Vilitkevich, kí wọ́n tó mú un

Àwọn ọlọ́pàá já wọlé Anatoliy Vilitkevich wọ́n sì mú un. Wọ́n sọ fún ìyàwó rẹ̀ “ó máa pẹ́” kó tó tún lè rí ọkọ rẹ̀. Àwọn aláṣẹ sọ pé ó ti rú Abala kejìlélọ́gọ́rin-lé-nígba (282), ìsọ̀rí kejì, apá kìíní nínú Òfin Ọ̀daràn torí pé ó ‘ń bá àjọ agbawèrèmẹ́sìn ṣètò iṣẹ́ wọn,’ á sì wà látìmọ́lé títí di June 2, 2018 kí ìgbẹ́jọ́ tó wáyé. Bí ilé ẹjọ́ bá dá a lẹ́bi, ó lè ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá.

March 2018, Oryol: Yàtọ̀ sí ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn tí wọ́n ń bá Dennis Christensen ṣe lọ́wọ́, lẹ́yìn táwọn aláṣẹ ti yẹ àwọn ilé méje kan wò ní Oryol ní May ọdún 2017, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Ẹlẹ́rìí míì, ìyẹn Sergey Skrynnikov. Wọn ò tíì sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Skrynnikov jẹ̀bi. Àmọ́ wọ́n ní ó tàpá sí Abala kejìlélọ́gọ́rin-lé-nígba (282), ìsọ̀rí kejì, apá kejì nínú Òfin Ìwà Ọ̀daràn torí pé ó ‘ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àjọ agbawèrèmẹ́sìn.’ Tí ilé ẹjọ́ bá sọ pé ó jẹ̀bi, ó máa lò tó ọdún méjì sí mẹ́rin lẹ́wọ̀n.

February 7, 2018, Belgorod: Àwọn ọlọ́pàá rẹpẹtẹ já wọlé ó kéré tán, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́wàá. Àwọn ọlọ́pàá yìí ti àwọn tó ń gbé nínú àwọn ilé náà lulẹ̀ tàbí ki wọ́n fún wọn mọ́ ara ògiri. Wọ́n yẹ ilé wọn wò, wọ́n sì kó àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ wọn pẹ̀lú ìwé ìrìnnà, fọ́tò àti owó. Lẹ́yìn náà, wọ́n kó gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, wọ́n da ìbéèrè bò wọ́n, wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀, àfi Anatoly Shalyapin àti Sergei Voikov. Àwọn ọlọ́pàá ti àwọn ọkùnrin méjèèjì náà mọ́lé fún ọjọ́ méjì gbáko kí wọ́n tó fi wọ́n sílẹ̀. Wọ́n sì sọ pé àwọn méjèèjì ò gbọ́dọ̀ kúrò ní Belgorod lọ sí ibikíbi.

January 23, 2018, Kemerovo: Àwọn ọlọ́pàá já wọ ilé méjìlá wọ́n sì kó gbogbo ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́, ìwé ìsìn àti ọ̀pọ̀ ìwé míì tó wà níbẹ̀. Kí wọ́n tó já wọnú àwọn ilé náà, ọkùnrin kan tó ṣe bíi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun ti lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí, ó ti dọ́gbọ́n gba ohùn wọn sílẹ̀, ó sì fi lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́. Ohun táwọn ọlọ́pàá gbọ́ nínú ohùn tó gbà sílẹ̀ náà ni wọ́n gùn lé tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìwà ọ̀daràn.

Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lè Pín Àwọn Ìdílé Níyà

Tá a bá yọwọ́ àṣejù táwọn ọlọ́pàá àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò (FSB) ṣe yìí, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti pa á láṣẹ pé Ìjọba lè lọ kó ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí wọ́n lè ‘tún wọn kọ́ láti mọ̀wà hù láwùjọ.’ Ní November 14, 2017, Àpérò Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà sọ ọ́ dòfin, nínú Ìpinnu Kẹrìnlélógójì (44), pé ilé ẹjọ́ lè “fi ẹ̀tọ́ táwọn òbí ní dù wọ́n” bí wọ́n bá kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀sìn tí ìjọba bá ti kà léèwọ̀ pé ó jẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn.”

Ní November 23, 2017, Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ètò Ẹ̀kọ́ àti Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ gbé “àbá” kan jáde jákèjádò orílẹ̀-èdè náà tó ti sọ pé kí wọ́n ṣe “àtúnkọ́” fáwọn ọmọ tó bá ti wà nínú “ìlànà gbígba wèrè mẹ́sìn.” Ọmọ àwọn tó bá jẹ́ ara ẹgbẹ́ ISIS àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwùjọ àwọn ọmọdé méjì tí wọ́n ní ọ̀rọ̀ yìí kàn. Wọ́n sọ pé “ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́” ló jẹ́ ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ wọn ò tíì gba ọmọ Ẹlẹ́rìí kankan títí di báyìí.

Ibo Ni Gbogbo Wàhálà Yìí Máa Já Sí?

Kò tíì sí orílẹ̀-èdè míì lára Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù tó tíì gbé irú ìjà tó le tó báyìí ko àwọn ẹlẹ́sìn tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tí wọ́n ń sin Ọlọ́run láì dí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò lè pé jọ láti ìjọsìn ní gbangba tàbí kí wọn jọ ka Bíbélì, kí wọ́n sì jọ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Káwọn ọlọ́pàá má bàa mú wọn kí wọ́n sì bá wọn ṣẹjọ́ ìwà ọ̀daràn, àfi kí wọ́n máa sin Ọlọ́run ní bòókẹ́lẹ́, bó ṣe di dandan pé kí wọ́n ṣe nígbà ìjọba Soviet Union àtijọ́.

Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ní ọ̀rọ̀ àwọn ará wọn lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà jẹ lógún gan-an, wọ́n sì ń wo bí wàhálà tó lọ́wọ́ ìjọba nínú yìí ṣe máa bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ tó, bó ṣe máa nípa lórí ìjọsìn wọn àti bó ṣe máa rí lára wọn. Philip Brumley, tó jẹ́ Agbẹjọ́rò tó sábà máa ń ṣojú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ pé: “Ó yẹ kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fòpin sí ìyà tó fi ń jẹ àwọn èèyàn yìí, kó sì ṣe ojúṣe táráyé ń retí pé kó ṣe, ìyẹn ni pé kó má fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti òmìnira ìsìn dù wọ́n. Ní báyìí táwọn aláṣẹ ti fò fẹ̀rẹ̀ látorí gbígbéjà ko àjọ táwọn Ẹlẹ́rìí ń lò lábẹ́ òfin bọ́ sórí jíjù wọ́n sẹ́wọ̀n, kí ló tún kù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á máa retí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà?”