MARCH 1, 2018
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Ti Sún Ìgbẹ́jọ́ Dennis Christensen sí April 3, 2018
Ní February 26, 2018, Ilé Ẹjọ́ Zheleznodorozhniy nílùú Oryol bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ Dennis Christensen lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wón fi kàn án. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ alátìlẹ́yìn Ọ̀gbẹ́ni Christensen ló wà nílé ẹjọ́ lọ́jọ́ yẹn. Ẹlòmíì tó tún wà níbẹ̀ ni Jeanne Christina Demirci tó jẹ́ aṣojú ìjọba orílẹ̀-ède Denmark, àti ìlú Moscow ló ti rìnrìn àjò wá kó lè wà níbi ìgbẹ́jọ́ náà. Kò ju wákàtí kan lọ tí wọ́n fi gbọ́ ẹjọ́ náà. Adájọ́ Aleksey Rudnev fọwọ́ sí i pé kí ilé ẹjọ́ fún Ọ̀gbẹ́ni Christensen àtàwọn agbẹjọ́rò ẹ̀ ní àkókò díẹ̀ sí i kí wọ́n lè ráyè ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé tó dá lórí ẹjọ́ náà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ṣáájú ìgbẹ́jọ́ yẹn, Ilé Ẹjọ́ Sovetskiy fi ẹ̀tọ́ yìí dù ú, ọ̀sẹ̀ méjì péré ni wọ́n fún un pé kó fi ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé tó dá lórí ẹjọ́ náà lédè Rọ́ṣíà, tó ní ojú ìwé ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500]. Adájọ́ Rudnev ti sún ìgbẹ́jọ́ náà sí April 3, 2018, ní aago mẹ́wàá ààbọ̀ àárọ̀. Títí dìgbà yẹn, Ọ̀gbẹ́ni Christensen ṣì máa wà látìmọ́lé.