Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 7, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Saint Petersburg Wọ́gi Lé Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórí Ohun Ìní Wọn

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Saint Petersburg Wọ́gi Lé Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórí Ohun Ìní Wọn

Ní May 3, 2018, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Saint Petersburg wọ́gi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè kí ìjọba má bàa gbẹ́sẹ̀ lé ọ́fíìsì wọn tó wà ní Solnechnoye. Ní báyìí, ìjọba lè tẹ̀ lé ìpinnu ilé ẹjọ́ yìí, kí wọ́n sì gba ilé náà nígbàkigbà.

Ìpinnu ilé ẹjọ́ yìí fi hàn pé ó fara mọ́ ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Sestroretskiy ṣe pé wọ́n ti wọ́gi lé àdéhùn ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún (17) tí ohun ìní yìí fi di ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Bí wọ́n ṣe wọ́gi lé àdéhùn yìí mú kó ṣe kedere sí ilé ẹjọ́ pé ó ti pẹ́ tí ohun ìní yìí ti jẹ́ ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba lè gbẹ́sẹ̀ lé ohun ìní yìí torí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fòpin sí iṣẹ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà ní April 2017. “Ìdájọ́” tí kò tọ́ yìí ti fún ìjọba lágbára láti gba ohun ìní náà láìdìí.

Agbẹjọ́rò kan tó ń jẹ́ Philip Brumley, tó sábà máa ń ṣojú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ìpinnu yìí ò bá ìdájọ́ òdodo mu rárá. Ọlọ́run ni wọ́n ń lo ilé náà fún, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ń bójú tó iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nílẹ̀ Rọ́ṣíà láìdí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́. Ká kúkú sọ pé ńṣe ni ìjọba jí i mọ́ wọn lọ́wọ́, a sì máa gbé ọ̀rọ̀ ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù yìí lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.”