Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 20, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Ṣì Fòfin De Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní Rọ́ṣíà

Wọ́n Ṣì Fòfin De Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní Rọ́ṣíà

Lónìí, Ilé Ẹjọ́ Leningrad fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tá a pè lórí ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg dá fún wá lóṣù August, pé àwọn fòfin de Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà, tí wọ́n sì kéde pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n (30) èèyàn tó wà níbi ìgbẹ́jọ́ náà, tó fi mọ́ àwọn aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè Britain, Netherlands, Switzerland àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ọ̀pọ̀ ìgbà lásìkò tí ilé ẹjọ́ ń gbọ́ ẹjọ́ náà ni àwọn agbẹjọ́rò wa fi ẹ̀rí tó ṣe kedere han ilé ẹjọ́ láti fi hàn pé iṣẹ́ tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tílé ẹjọ́ yàn pé kí wọn ṣe àyẹ̀wò ṣe kò pójú owó, wọ́n sì tún gbè sápá kan nínú àyẹ̀wò wọn. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tílé ẹjọ́ yàn sọ pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì, torí kílé ẹjọ́ lè kéde pé ìwé “agbawèrèmẹ́sìn” ni.

Àwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n yìí sọ pé dandan, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kì í ṣe Bíbélì, torí pé wọn ò kọ ọ́ sínú ẹ̀ pé Bíbélì ni. Àmọ́, àwọn agbẹjọ́rò wa tọ́ka sí ojú ìwé karùn-ún Bíbélì náà tí wọ́n ṣe jáde lọ́dún 2007 lédè Rọ́ṣíà, níbi tí wọ́n kọ ọ́ sí gbàǹgbà-gbangba pé: “A ṣẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ Bíbélì yìí sí èdè Rọ́ṣíà ni.” Àwọn agbẹjọ́rò wa bi àwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n pé báwo ni wọ́n á ṣe fi ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín mẹ́tàlá [287] ọjọ́ ṣàyẹ̀wò Bíbélì yìí, síbẹ̀ tí wọn ò rí gbólóhùn yìí tó wà ní ìpínrọ̀ kẹta nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

Nígbà tí wọ́n bi ọ̀kan lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí ilé ẹjọ́ yàn láti ṣe àyẹ̀wò yìí ní ìbéèrè, ṣe ló tún ń ránnu mọ́ ohun tó ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a ò lè ka Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí Bíbélì àfi tí “olórí ẹ̀sìn ilẹ̀ náà bá súre fún un” tàbí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bá bá Bíbélì tó ti wà tẹ́lẹ̀ mu gẹ́lẹ́. Àwọn tó pera wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ọ̀hún tún sọ pé àwọn ò fara mọ́ bí Bíbélì náà ṣe lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, wọ́n sì sọ pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì náà ò bá àwọn ẹ̀kọ́ kan tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni mu. Àwọn agbẹjọ́rò wa dábàá fún ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n yan àwọn míì tó máa tún àyẹ̀wò Bíbélì náà ṣe, àmọ́ adájọ́ ò gba ọ̀rọ̀ wọn wọlé.

Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn ará wa pè lónìí, kò sí ibòmíì tí àwọn ará wa lè gbẹ́ ọ̀rọ̀ náà lọ mọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, àfi kí wọ́n gbé e lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.

Ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lójú pé kò sí èèyàn kankan tó lè gbá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọlẹ̀, ó sì dá wọn lójú hán-ún hán-ún pé ohun táwọn aláṣẹ rawọ́ lé báyìí kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè kógbá wọlé ò ní yọrí sí rere.—Aísáyà 40:8.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000