Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 17, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Sọ Pé Kí Ìjọba Fòfin De Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlú Míì Lórí Ẹ̀sùn Pé Agbawèrèmẹ́sìn Ni Wọ́n

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Sọ Pé Kí Ìjọba Fòfin De Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlú Míì Lórí Ẹ̀sùn Pé Agbawèrèmẹ́sìn Ni Wọ́n

Ní February 9, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ pé kí ìjọba fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Birobidzhan. Ilé ẹjọ́ kan ti gbọ́ ẹjọ́ náà tẹ́lẹ̀, wọ́n ní agbawèrèmẹ́sìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú yẹn, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n ṣe ẹ̀sìn wọn. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà wá fọwọ́ sí ẹjọ́ tí wọ́n dá yẹn.

Ṣe ni wọ́n lọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí mọ́ wọn lẹ́sẹ̀. Ní February 2015 àti January 2016, àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yá, tí wọ́n ti ń ṣèjọsìn, wọ́n sì lọ tọ́jú àwọn ìwé tí ìjọba ti fòfin dè síbẹ̀ fúnra wọn. Àwọn ọlọ́pàá yìí wá pa dà lọ tú ilé náà nígbà tó yá, wọ́n sì sọ pé àwọn “rí” ẹrù òfin níbẹ̀. Bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní January yẹn ṣe wáyé rè é: àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó fi nǹkan bojú ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé lọ́wọ́, wọ́n sì dọ́gbọ́n fi ìwé tí ìjọba fi fòfin dè sábẹ́ àga kan níṣojú àwọn tó wà níbẹ̀.

Láti ìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow ti sọ pé ohun tí Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà sọ lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, pé àwọn máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí pa, ìlú Birobidzhan tó wà ní Àgbègbè Olómìnira Àwọn Júù ní Rọ́ṣíà, ni wọ́n ti máa kọ́kọ́ fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.