APRIL 13, 2016
RỌ́ṢÍÀ
Wọ́n Dájú Sọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, Wọ́n sì Ti Ń Fojú Ba Ilé Ẹjọ́ Lẹ́nu Àìpẹ́ Yìí
Ìlú Taganrog, ní Àgbègbè Rostov. Ní March 17, 2016, Ilé Ẹjọ́ tó wà ní Rostov fọwọ́ sí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ìlú ti kọ́kọ́ dá pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlógún [16] jẹ̀bí torí pé wọ́n ń ṣèjọsìn. Àmọ́ Ilé Ẹjọ́ Rostov dín owó ìtanràn tí wọ́n bù lé méjìlá [12] nínú wọn kù sí 10,000 rubles (tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] owó náírà). Wọn ò tún rán wọ lọ sẹ́wọ̀n. A ò tíì mọ ipa tí ìgbésẹ̀ méjèèjì tí ilé ẹjọ́ yìí gbé ṣì máa ni.
Agbẹjọ́rò fẹ́ kí ìjọba kéde pé ìwé àwọn “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì. Agbẹjọ́rò tó ń rí sí ọ̀rọ̀ Ìkẹ́rù nílùú Leningrad-Finlyandskiy kọ̀wé láti gbé ẹ̀sùn dìde kí ìjọba lè kéde pé ìwé àwọn “agbawèrèmẹ́sìn” ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde. Ìyẹn sì ta ko ohun tó wà nínú Àpilẹ̀kọ 3-1 nínú Òfin tí ìjọba ṣe lórí Bí Wọ́n Ṣe Lè Gbéjà Ko Àwọn Agbawèrèmẹ́sìn, èyí tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi òfin náà de Bíbélì. Ó ṣe kedere pé Bíbélì ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àmọ́ ohun tí agbẹjọ́rò yìí gùn lé tó fi ń kẹ́wọ́ ni pé àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì tó bá “àwọn àṣà mímọ́” Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà mu nìkan la lè kà sí Bíbélì. Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg ti sún ẹjọ́ náà sí April 26, 2016.