Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 19, 2016
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn, Ìdájọ́ Òdodo Ni Wọ́n Fẹ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn, Ìdájọ́ Òdodo Ni Wọ́n Fẹ́

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow ti ṣètò láti gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà pè lórí ọ̀rọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn tí àwọn aláṣẹ fẹ́ tì pa, torí àwọn Ẹlẹ́rìí fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí àwọn aláṣẹ fẹ́ ṣe yìí bófin mu. Tó bá di January 16, 2017, ní aago mọ́kànlá kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá àárọ̀ lórí aago ìlú Moscow, ilé ẹjọ́ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọjọ́ yẹn náà ni wọ́n máa dá ẹjọ́ náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ò jẹ̀bi ẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” tí wọ́n fi kan àwọn, pé ṣe ni àwọn aláṣẹ ìlú hùmọ̀ ẹ̀, wọ́n sì fẹ́ lọ́ irọ́ mọ́ àwọn lẹ́sẹ̀ kí wọ́n lè mú àwọn ní ọ̀daràn bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn. Nínú ẹjọ́ tó wáyé ní October 12, 2016, M. S. Moskalenko tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Tverskoy nílùú Moscow ò jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ẹnì kankan wá jẹ́rìí sọ́rọ̀ náà, kò sì gbà kí wọ́n fi fídíò tó tú àṣírí ìwàkiwà táwọn aláṣẹ kan hù hàn.

James Andrik tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kárí ayé sọ pé: “Ibi yòówù kí ẹjọ́ yìí já sí, ọ̀kan pàtàkì ló máa jẹ́. Tí Ilé Ẹjọ́ Ìlú Moscow bá dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi, Ọ́fíìsì Agbẹjọ́rò Àgbà máa ṣe ohun tí wọ́n láwọn fẹ́ ṣe sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n lè tì í pa, kí wọ́n wá túbọ̀ máa halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì fòfin de ẹ̀sìn wọn ní gbogbo Rọ́ṣíà. Àmọ́ tí ilé ẹjọ́ bá dá wọn láre, a jẹ́ pé ìdájọ́ òdodo lékè nìyẹn, ìgbà ọ̀tun sì máa dé.”