Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 5, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Wọ́n Máa Gbọ́ Ẹjọ́ nípa Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Gbẹ́sẹ̀ Lé ní Rọ́ṣíà

Wọ́n Máa Gbọ́ Ẹjọ́ nípa Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Gbẹ́sẹ̀ Lé ní Rọ́ṣíà

Ìjọba Rọ́ṣíà ti fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé tí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò èyí tó wà ní ìlú Solnechnoye nítòsí ìlú St. Petersburg. Àwọn ilé yìí ni wọ́n ti ń darí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

Ní April 20, 2017, ilé ẹjọ́ gíga pàṣẹ pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ilé tí ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Àmọ́ àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania (WTPA), tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ni àwọn ilé yìí. Ohun tí adájọ́ fẹ́ ṣe ni pé, ó fẹ́ kí wọ́n wọ́gi lé àdéhùn ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] tí wọ́n ṣe nígbà tí àwọn ilé náà di ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvani (WTPA). Ṣáájú kí adájọ́ tó dá ẹjọ́ yìí, ìjọba ò sọ ọ́ rí pé àdéhùn náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, àjọ WTPA náà sì ń san owó orí lórí àwọn ilé náà látìgbà tó ti di tiwọn. Nísinsìnyí, ìjọba ń wá gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ilé náà, kí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.

Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ yìí ní November 29, 2017, adájọ́ ò ka ọ̀rọ̀ àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí pàtàkì, ọ̀rọ̀ agbẹjọ́rò tó ṣojú fún ìjọba nìkan ló kà sí. Tá a bá díye lé àwọn ilé yìí, ìníyelórí wọn tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù owó dọ́là. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ń gbé àwọn ilé yẹn fẹ́ẹ̀ tó irínwó [400], àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n, àwọn kan sì ti ń gbé ibẹ̀ fún ohun tó lé ní ogún ọdún [20]. Kò rọrùn fún wọn rárá láti kúrò ní ibi tí wọ́n ń gbé, tí wọ́n sì tí ń ṣiṣẹ́ sin àwọn arákùnrin wọn ní orílẹ̀-èdè wọn ní Rọ́ṣíà.

Tó bá di December 7, 2017 ní aago méjì ọ̀sán [2:00 p.m] wọ́n tún máa gbọ́ ẹjọ́ yìí ní ilé ẹjọ́ gíga Sestroretskiy tó wà ní St. Petersburg.