Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 3, 2018
RỌ́ṢÍÀ

Wọn Ò Gba Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Pè Wọlé, Ó sì Mú Kí Àwọn Aláṣẹ Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Àtijọ́

Wọn Ò Gba Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Pè Wọlé, Ó sì Mú Kí Àwọn Aláṣẹ Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Àtijọ́

Ní Thursday, May 3, 2018, Ilé Ẹjọ́ Saint Petersburg fọwọ́ sí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ ṣe ní December 2017, wọ́n ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àtijọ́ tó wà ní Solnechnoye lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè dá ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dúró kí wọ́n má gba ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti gbọ́ sí ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá fún wa lónìí, wọ́n sì ti ń gbé e yẹ̀ wò. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti kàn sí ìjọba Rọ́ṣíà pé ẹjọ́ wa wà lára ẹjọ́ táwọn kọ́kọ́ ń fún láfiyèsí.

Ojú Jèhófà, Ọlọ́run tó máa ń dá gbogbo ẹjọ́ bó ṣe tọ́ là ń wò báyìí. A retí pé tó bá tó àkókò lójú ẹ̀, ó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà.​—Aísáyà 30:18.