Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 24, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Tún Sọ Pé Kí Dennis Christensen Ṣì Wà Látìmọ́lé

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol Tún Sọ Pé Kí Dennis Christensen Ṣì Wà Látìmọ́lé

IBI TỌ́RỌ̀ DÉ BÁYÌÍ: Ní December 22, 2017, Ilé Ẹjọ́ Oryol fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Christensen pé kí wọ́n lè dá a sílẹ̀ ní àtìmọ́lé tí wọ́n fi sí kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. February 23, 2018 ni ọjọ́ tí wọ́n dá pé ó máa lò látìmọ́lé máa pé, á tún wá fojú ba ilé ẹjọ́, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án níbẹ̀.

Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí ilé ẹjọ́ Sovietskiy nílùú Oryol lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti gbẹ́jọ́ Ọ̀gbẹ́ni Dennis Christensen ní November 20, 2017, ilé ẹjọ́ ní kó ṣì wà látìmọ́lé di February 23, 2018. Ìgbà kejì rèé tí ilé ẹjọ́ máa fi oṣù mẹ́ta kún àtìmọ́lé Ọ̀gbẹ́ni Christensen. May 2017 làwọn ọlọ́pàá mú un nígbà tí wọ́n ya wọ ibì kan tí òun àti àwọn míì ti ń ṣèpàdé ẹ̀sìn wọn nírọwọrọsẹ̀ nílùú Oryol, àtìgbà yẹn ni wọ́n sì ti tì í mọ́lé láìgbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.

Ọmọ ilẹ̀ Denmark ni Ọ̀gbẹ́ni Christensen, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni. Kí wọ́n tó mú un, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Ilé ẹjọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni yìí tún sọ pé kó ṣì wà látìmọ́lé kí àwọn tó ń ṣèwádìí lè ráyè kó “ẹ̀rí” jọ láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń ṣe ìjọsìn tí kò bófin mu. Ilé ẹjọ́ ò gbà pé kó máa ti ilé wá jẹ́jọ́ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi ń ṣèwádìí. Ìjọba ilẹ̀ Denmark tiẹ̀ tún fi dá wọn lójú pé àwọn ò ní fún Ọ̀gbẹ́ni Christensen ní ìwé ìrìnnà tó lè fi kúrò ní Rọ́ṣíà, àwọn ò sì ní ṣe agbódegbà fún un táá fi sá lọ, àmọ́ ilé ẹjọ́ ṣì fàáké kọ́rí pé àwọn ò gbà kó máa tilé wá jẹ́jọ́.

Nígbà tí wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Christensen, ṣe lòun àti ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Rọ́ṣíà ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin pé wọ́n lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn, kí wọ́n sì kóra jọ pẹ̀lú àwọn míì. Ilé ẹjọ́ lè pàṣẹ pé kó ṣì wà látìmọ́lé fún ọdún méjì kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Tí wọ́n bá sọ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, ó lè fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá gbára.