Rọ́ṣíà
Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́síà Kéde Pé Ìwé “Agbawèrèmẹ́sìn” Ni Bíbélì
Ilé Ẹjọ́ Ìlú Vyborg kéde pé ìwé ‘agbawèrèmẹ́sìn’ ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́síà, ìyẹn Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde lóríṣiríṣi èdè.
Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Sọ̀rọ̀ Lórí Bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ṣe Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn iléeṣẹ́ ìjọba àtàwọn aláṣẹ kárí ayé sọ̀rọ̀ lórí ẹjọ́ tí kò tọ́ tí ilé ẹjọ́ dá fáwọn Ẹlẹ́rìí àti bí ìjọba Rọ́ṣíà ò ṣe jẹ́ káwọn ẹlẹ́sìn kéékèèké lómìnira ẹ̀sìn.
Àwọn Aṣojú Kárí Ayé Ti Àwọn Ará Wa ní Rọ́ṣíà Lẹ́yìn Níbi Ìgbẹ́jọ́ Tó Wáyé ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣètò pé kí àwọn arákùnrin láti ilẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé rìnrìn àjò lọ sílùú Moscow láti ṣojú ẹgbẹ́ ará.
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Kò Yíhùn Pa Dà Lórí Ẹjọ́ tí Wọ́n Dá Fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tẹ́lẹ̀
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn Ẹlẹ́rìí pè, wọ́n sì sọ pé àwọn ò yíhùn pa dà lórí ẹjọ́ táwọn kọ́kọ́ dá ní April 20. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù àti Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè.
Àwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà Gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Títí Kan Ọmọ Ilẹ̀ Denmark Tó Wà Lẹ́wọ̀n, Pé Wọ́n Ran Ìlú Lọ́wọ́
Àwọn aláṣẹ ìlú Oryol dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n ṣeun bí wọ́n ṣe ran ìlú lọ́wọ́. Dennis Christensen, tí wọ́n mú lẹ́nu àìpẹ́ yìí torí pé ó ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀, wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí yìí.
Fídíò Kan Jáde Lórí Bí Àwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà Ṣe Ya Wọ Ibi Táwọn Ẹlẹ́rìí Ti Ń Ṣèpàdé ní Ìrọwọ́rọsẹ̀
Iléeṣẹ́ ìròyìn kan ní Rọ́ṣíà gbé fídíò kan jáde lórí bí àwọn ọlọ́pàá tó dira ogun àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ṣe ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nílùú Oryol, ní Rọ́ṣíà.
Fídíò Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Tó Ya Wọ Ibi Táwọn Ẹlẹ́rìí Ti Ń Ṣèpàdé ní Ìrọwọ́rọsẹ̀
Ní May 25, 2017, àwọn ọlọ́pàá tó dira ogun àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn nílùú Oryol, ní Rọ́ṣíà.
Ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Dá Ń Ní Ipa tí Kò Dáa Lórí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí ń ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó sì ti jẹ́ káwọn èèyàn kan àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba túbọ̀ máa fìyà jẹ wọ́n, àpẹẹrẹ rẹ̀ la rí nínú àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ yìí.
Ààrẹ Putin Fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ”
Ní ìgbà ayẹyẹ kan ní Kremlin, Ààrẹ orílè-èdè Rọ́ṣíà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vladimir Putin fún Valeriy àti Tatiana Novik, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìlú Karelia, ní àmì ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ.”
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Máa Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́run Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní July 17, 2017
Lára ohun tó wà nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà ni pé kí wọ́n yí òfin tí wọ́n ti dá fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa dà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ohun tí wọ́n torí ẹ̀ dá wa lẹ́jọ́ kò jóòótọ́, àti pé wọ́n sọ pé agbawèrèmẹ́sìn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sì ṣe agbawèrèmẹ́sìn.