Rọ́ṣíà
Àwọn Aláṣẹ Kìlọ̀ Fáwọn Ẹlẹ́rìí Pé Àwọ́n Máa Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wọn Pa ní Rọ́ṣíà, Èyí Ò sì Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Lómìnira Ẹ̀sìn
Ó ṣeé ṣe kó wá di pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà á lómìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́, àmọ́ wọn ò ní lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn.
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Fẹ́ Ṣe Ohun tí Ò Ṣẹlẹ̀ Rí, Wọ́n Fẹ́ Ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Náà Pa
Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kọ lẹ́tà láti kìlọ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn máa fòfin de ẹ̀sìn wọn ní Rọ́ṣíà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìrọwọ́rọsẹ̀ ni wọ́n ń ṣe é.
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè Sọ Pé Ìjọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ń Lo Òfin Láti Fẹ̀sùn Agbawèrèmẹ́sìn Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń fi òfin ta ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n.
Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Ò Fọwọ́ sí Bí Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ṣe Fòfin De Ìkànnì JW.ORG
Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nìkan ni wọ́n ti fòfin de ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ìyẹn jw.org lágbàáyé, wọ́n fòfin dè é ní July 21, 2015.
Wọ́n Ní Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pa Dà Sílé Ẹjọ́ Nílùú Taganrog—Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Báyìí?
Ṣé wọ́n máa fi àwọn ọmọ Rọ́ṣíà mẹ́rìndínlógún tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí sẹ́wọ̀n láì mọwọ́ mẹsẹ̀ torí pé wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́?
Ẹlẹ́rìí Kan Ní Rọ́ṣíà Rí 6,000 Owó Ilẹ̀ Yúróòpù He, Ó sì Dáa Pa Dà Fẹ́ni Tó Ni Ín
Svetlana Nemchinova, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sapá gan-an kó lè rí ẹni tó ni owó tabua tí wọ́n ṣèèṣì dànù mọ́ ilẹ̀.