Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Rọ́ṣíà

 

2020-09-03

RỌ́ṢÍÀ

A Gbọ́rọ̀ Látẹnu Arákùnrin Dmitriy Mikhaylov

Wọ́n fàṣẹ ọba mú arákùnrin Mikhaylov ní May 29, 2018, ó sì lo ọ̀pọ̀ oṣù látìmọ́lé. Nígbà tá a jọ ń sọ̀rọ̀, ó sọ bí Jèhófà ṣe ran òun lọ́wọ́ láti fara dà á àti bí ìyàwó òun ṣe ti òun lẹ́yìn. Ó tún sọ pé nǹkan míì tó fún òun láyò, tó sì jẹ́ kọ́kàn òun balẹ̀ ni bí òun ṣe ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn míì lẹ́wọ̀n.