Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Apá òsì: Fọ́tò Cecilia Alvarez nínú ìwé ìròyìn nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kẹtàdínlógún (17); Apá ọ̀tún: Cecilia pẹ̀lú àwọn òbí rẹ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin ní May 2019

AUGUST 7, 2019
AJẸNTÍNÀ

Ọmọ Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) Ni Arábìnrin Cecilia Alvarez, Àmọ́ Ó Ti Ṣe Iṣẹ́ Abẹ Mẹ́tàlélógójì (43) Láì Gba Ẹ̀jẹ̀

Ọmọ Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) Ni Arábìnrin Cecilia Alvarez, Àmọ́ Ó Ti Ṣe Iṣẹ́ Abẹ Mẹ́tàlélógójì (43) Láì Gba Ẹ̀jẹ̀

Orílẹ̀-èdè Argentina ni wọ́n bí Arábìnrin Cecilia Alvarez sí. Ó sì ti kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro àìlera tó le gan-an. Kò ju ọmọ ọjọ́ mẹ́rìndínlógún (16) lọ nígbà tó ṣe iṣẹ́ abẹ àkọ́kọ́. Ní May 18, 1994, àwọn dókítà ní orílẹ̀-èdè Argentina ṣiṣẹ́ abẹ láti ṣàtúnṣe sí àléébù kan tó wà lórí ọ̀pá ẹ̀yìn àti awọ fẹ́lẹ́ tó bo egungun ẹ̀yìn rẹ̀. Ní báyìí, Cecilia ti pé ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), ó ti ṣe iṣẹ́ abẹ mẹ́tàlélógójì (43), ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ ló sì jẹ́ nígbà tó wà lọ́mọdé. Ó tiẹ̀ ṣe iṣẹ́ abẹ kan láìpẹ́ yìí níbi tí wọ́n ti ṣàtúnṣe egungun ìbàdí apá òsì rẹ̀. Bíi tàwọn iṣẹ́ abẹ míì tó ti ṣe tẹ́lẹ̀, wọ́n ṣe èyí náà láṣeyọrí láì fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára.

1999: Cecilia nígbà tó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún ní ilé ìwòsàn àwọn ọmọdé, ìyẹn Juan P. Garrahan Children’s Hospital

Cecilia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ tí mo ti ṣe sẹ́yìn àtàwọn ìtọ́jú tí mo ti gbà tán mi lókun gan-an.” Àmọ́, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó sì gbára lé Jèhófà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀, ó ń sapá láti ṣe àwọn ohun tí àwọn dókítà bá sọ pé kó ṣe. Cecilia sọ pé: “Ohun kan tí mo máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ni pé, mó máa ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ abẹ. Ìyẹn gba pé kí n lo àwọn oògùn ẹ̀jẹ̀, kí n sì jẹ àwọn oúnjẹ tí á mú kí sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i.”

Nígbà tí Cecilia ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn onímọ̀ ìṣègùn ṣe ràn án lọ́wọ́ láti ọdún yìí wá, ó sọ pé: “Mo mọyì iṣẹ́ wọn gan-an, kì í ṣe torí pé wọn gba ẹ̀mí mi là nìkan, ṣùgbọ́n torí pé wọn tún fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìpinnu mi láti má ṣe gba ẹ̀jẹ̀.”

Dókítà Ernesto Bersusky, ẹni tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ìṣègùn egungun ẹ̀yìn tó lábùkù

Àwọn onímọ̀ ìṣègùn tó tọ́jú Cecilia bọ̀wọ̀ fún òun àtàwọn ará tó ràn án lọ́wọ́. Dókítà Ernesto Bersusky, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olórí àwọn tó ń tọ́jú egungun ẹ̀yìn ní ilé ìwòsàn àwọn ọmọdé tó ń jẹ́ Juan P. Garrahan Children’s Hospital nílùú Buenos Aires, tó ti ṣiṣẹ́ abẹ egungun ẹ̀yìn fún Cecilia lọ́pọ̀ ìgbà sọ pé: “Kò sígbà tí mo fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún Cecilia, tí kì í wú mi lórí láti rí bó ṣe fọwọ́ pàtàkì mú ìpinnu rẹ̀ àti bó ṣe máa ń ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀ láì fìkan pe méjì. Mo ti bá a sọ̀rọ̀ láìmọye ìgbà, tí màá sì ṣàlàyé àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe, ìyẹn nìkan kọ́, máà tún fi í lọ́kàn balẹ̀ pé a ò ní fàjẹ̀ sí i lára.”

Dókítà Susana Ciruzzi, agbẹjọ́rò àti onímọ̀ nípa ìlànà ìwà híhù nílé ìwòsàn

Dókítà Susana Ciruzzi, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àti ọkàn lára ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìwà tó yẹ káwọn oníṣègùn máà hù ní ilé ìwòsàn ọmọdé tó ń jẹ́ Juan P. Garrahan Children’s Hospital sọ pé: “Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn onímọ̀ ìṣègùn kì í ṣe kékeré. A ti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ti fi ara wa jìn láti yí èrò, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ pa dà, nípa bẹ́ẹ̀, èyí ti jẹ́ ká ṣàwárí àwọn ìtọ́jú míì téèyàn lè yàn dípò fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára.”

Gẹ́gẹ́ bí Cecilia ṣe sọ, láfikún sí báwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀ ìṣègùn ṣe sapá ribiribi, ó tún gbóríyìn fún bí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe dúró tì í gbá-gbá-gbá, ó sọ pé: “Mi ò mọ bí mi ò bá ṣe dúpẹ́ fún iṣẹ́ takuntakun tí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) àti Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò ṣe. Láìka pé àwọn arákùnrin yìí ní ìdílé tiwọn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ń bójú tó sí, síbẹ̀ wọ́n ló okun àti àkókò wọn, torí kò sígbà tá a nílò wọn tí wọ́n sọ pé ó sú àwọn rí. Mo mọyì wọn gan-an.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo ìgbà ni ara máa ń ro Cecilia tó sì jẹ́ pé orí kẹ̀kẹ́ arọ ló máa ń wà nígbà gbogbo, ó ti pé ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) báyìí síbẹ̀ ó gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, kò sì ro ara rẹ̀ pin. Kódà, ó tiẹ̀ sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí ti túbọ̀ sọ mí di ẹni ọ̀tún, ó sì ti jẹ́ kí n lè máa gbé àwọn ànímọ́ Kristẹni yọ.”

July 2019: Cecilia wà lóde ẹ̀rí pẹ̀lú aṣáájú ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀

Cecilia tún sọ pé: “Lẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ abẹ tí mo ṣe, ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn bẹ̀ mí wò, ó sì tọ́ka sí Òwe 10:22 tó sọ pé: ‘Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora [tó máa wà títí láé] kún un.’ Kò sígbà tí mi ò kì í rántí àwọn ọ̀rọ̀ yìí.”

Ní May 1, 2019, Arábìnrin Cecilia rí ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ kan gbà nígbà tí ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ó hàn kedere pé, Jèhófà ti tu arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí nínú, ó sì tún fún un lókun. Nípa bẹ́ẹ̀, òun náà ń fi tayọ̀tayọ̀ sọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíì.

A nígbàgbọ́ pé bí Jèhófà ṣe tú Cecilia nínú, bẹ́ẹ̀ náà láá máa tu gbogbo wa nínú láìka onírúurú ìpọ́njú tó lè dé bá wa sí.​—2 Kọ́ríńtì 1:4.