APRIL 29, 2019
AJẸNTÍNÀ
Iṣẹ́ Ti Bẹ̀rẹ̀ Lórí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun ní Ajẹntínà
Lóṣù August 2018, iṣẹ́ ìkọ́lẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tuntun tó wà ní ìlú Buenos Aires, lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà. Ilé tuntun yìí máa ní àyè ibi iṣẹ́ mẹ́rìndínlógóje (136) àti ilé gbígbé méjì tó ní yàrá méjìndínlọ́gọ́rùn-ún (98). Ilé yìì yàtò sáwọn ilé tó wà káàkiri tí à ń lò fún ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí torí pé ibì kan náà ni ilé tuntun yìí wà, èyí máa mú kí iṣẹ́ yá, kó sì túbọ̀ rọrùn. Nínú àwọn fọ́tò tó wà nísàlẹ̀ yìí, ẹ máa rí bí iṣẹ́ náà ṣe lọ sí nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.
August 2018: The design team, staffed by ten brothers and sisters, worked for 18 months to prepare the architectural plans.
September 2018: Wọ́n gbẹ́ àwọn ihò tó jìn gan-an wọnú ilẹ̀, àwọn òpó tó lágbára ló máa wà nínú ihò náà kí ìpìlẹ̀ ilé náà lè ríbi fìdí múlẹ̀ dáadáa. Nítorí irú ilẹ̀ tó wà níbẹ̀, wọ́n máa ri òpó mẹ́tàlélọ́gọ́rùn-ún (103) mọ́lẹ̀, ó sì máa wọlẹ̀ tó mítà méjìdínlógójì.
November 2018: Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbé nǹkan látòkè tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó ga tó mítà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) tàbí ẹsẹ̀ bàtà méjìdínláàádọ́fà (108)..
November 2018: Wọn ò fọ̀rọ̀ ààbò ṣeré nígbà tí wọ́n ń to ẹ̀rọ tó ń gbé nǹkan látòkè, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn nígbà gbogbo bí iṣẹ́ náà ṣe ń lọ.
January 2019: Wọ́n ń fi àwọn ẹ̀rọ ńlá gbẹ́ ojú ibi tí wọ́n máa gbé ẹ̀rọ tó máa ń lọ sókè sódò sí.
March 2019: “Wọ́n to irin sílẹ̀ kí wọ́n tó da kankéré ìpìlẹ̀ ilé sórí rẹ̀ kó lè lágbára dáadáa.