OCTOBER 14, 2019
AJẸNTÍNÀ
Ibi Tá A Bá Iṣẹ́ Ìkọ́lé Bẹ́tẹ́lì Tó Wà ní Argentina Dé
Iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Argentina bẹ̀rẹ̀ ní ọdún kan ó lé díẹ̀ sẹ́yìn, iṣẹ́ náà sì ti kọjá ìlàjì báyìí. Ilé mẹ́ta ni ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí ní, ilé kan jẹ́ ọ́fíìsì, méjì tó kù sì jẹ́ ilé gbígbé, a sì kọ́ àwọn ilé náà sórí ilẹ̀ tó fẹ̀ tó éékà méjì. July 2020 la retí pé kí iṣẹ́ náà parí.
Inú wa dùn bá a ṣe ń rí i tí iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí ń tẹ̀síwájú lórílẹ̀-èdè Argentina. A gbàdúrà pé kí Jèhófà túbọ̀ máa bùkún iṣẹ́ ìkọ́lé náà.—Diutarónómì 28:8.
April 2019: Àwòrán ilé ọ́fíìsì tá a yà látòkè. Àwọn òpó tí a rí ní ìsàlẹ̀ ilé náà máa ga dé àjà tó kẹ́yìn kí ilé náà lè dúró digbí.
June 2019: Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ dúró lórí àkàbà láti mọ òpó fún Ilé Gbígbé A
July 2019: Àwọn òṣìṣẹ́ ń to irin àti àwọn ohun èlò amúnáwá ní àjà kẹta ilé tí àwọn ọ́fíìsì wà.
July 2019: Àwọn òṣìṣẹ́ ń da kankéré àjà kejì Ilé Gbígbé A. Ilé yìí máa ní àjà márùn-ún àti àyè téèyàn lè jókòó sí.
July 2019: Àwòrán bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí ibi ìgbọ́kọ̀sí. Ibi ìgbọ́kọ̀sí yìí máa gba ọkọ̀ méjìléláàádọ́rin (72) ní abẹ́ ilẹ̀ àti ọkọ̀ méjìléláàádọ́rin (72) lókè
August 2019: Ilé Gbígbé A ló wà lápá òsì yìí, Ilé Gbígbé B àti ọ́fíìsì ló wà lọ́ọ̀ọ́kán yẹn.