DECEMBER 10, 2019
ALBANIA
Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára Wáyé Lórílẹ̀-Èdè Albania
Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kú tàbí tó fara pa nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ tó tíì lágbára jù lọ láti bí ogójì ọdún sẹ́yìn wáyé lórílẹ̀ èdè Albania. Àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ba ilé àwọn ará wa márùndínlógójì (35) àti Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta jẹ́.
Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lékenkà yìí ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Albania ní November 26, 2019. Ìmìtìtì náà pa èèyàn mọ́kànléláàádọ́ta (51), àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ló fara pa, àwọn tó sì pàdánù ilé wọn kò lóǹkà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ìmìtìtì ilẹ̀ yìí ba ilé wọn jẹ́ ti lọ ń gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí àwọn ará ní ìjọ míì. Àwọn ìjọ tí ìmìtìtì yìí sì ba Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn jẹ́ lọ ń ṣèpàdé ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà láwọn ibi tí àjálù yìí kò dé.
Alàgbà kan ṣàlàyé bí ìmúrasílẹ̀ tí òun ti ṣe ṣáájú ṣe ran ìdílé òun lọ́wọ́ nígbà àjálù náà, ó sọ pé: “Gbàrà tí ìmìtìtì yìí wáyé, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ la nawọ́ gbé ‘báàgì pàjáwìrì’ wa, tá a sì sá jáde kúrò nínú ilé. A rí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì tá a kó sínú báàgì náà lò, àwọn nǹkan bíi: aṣọ ìbora, omi, oògùn àti oúnjẹ. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún bí wọ́n ṣe ń fi ìfẹ́ bójú tó wa.”
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ làwọn Alábòójútó Àyíká ti lọ sáwọn ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣọṣẹ́ láti lọ fún àwọn ará níṣìírí. Ìmìtìtì ilẹ̀ yìí ba ibi tí Alábòójútó Àyíká kan àti ìyàwó rẹ̀ ń gbé jẹ́. Láìka ìyẹn sí, ṣe ni Alábòójútó Àyíká yìí àti ìyàwó rẹ̀ lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fún àwọn ará míì níṣìírí.
Àwọn arákùnrin tí wọ́n wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tún lọ ṣèbẹ̀wò sáwọn ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ti ṣọṣẹ́ jù lọ. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti ń rí sí bí wọ́n á ṣe ṣèrànwọ́.
Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa ní Albania lè fara da ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bára dé yìí. À ń retí ìgbà tí àjálù kankan kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.—Róòmù 8:25.