Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 11, 2019
ALBANIA

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Albanian

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Albanian

Ní December 8, 2019, Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Albanian níbi àkànṣe ìpàdé kan tó wáyé ní Asllan Rusi Sports Palace, tó wà nílùú Tirana, lórílẹ̀-èdè Albania. *

Ó tó mílíọ̀nù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (2,900,000) èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Albania. Àmọ́, àwọn tó ń sọ èdè Albanian kárí ayé tó nǹkan bíi mílíọ̀nù méje àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (7,600,000) . Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dá ìjọ àti àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè Albanian sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Austria, Belgium, Kánádà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ilẹ̀ Faransé, Jámánì, Gíríìsì, Ítálì, North Macedonia, Sweden, Switzerland, Turkey àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe yìí máa wúlò fún àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (5,800) tó wà láwọn ìjọ tó ń sọ èdè Albanian nílùú Albania àtàwọn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì.

Àwọn ohun míì tó wà nínú Bíbélì tá a tún ṣe yìí ni àwọn àfikún, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, àlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì àti àwọn àwòrán ilẹ̀. A bá àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ń sọ èdè Albanian yọ̀ pé àwọn náà ti ní ìtumọ̀ Bíbélì tá a fi èdè tó bágbà mu kọ, tó rọrùn kà, tó sì ṣe kedere.​—Mátíù 13:16.

^ ìpínrọ̀ 2 A mú odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Albanian lọ́dún 2005.