Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 9, 2016
ÀMÉNÍÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Kọ́kọ́ Ṣe Iṣẹ́ Àṣesìnlú Lórílẹ̀-èdè Àméníà Ti Parí Ẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Kọ́kọ́ Ṣe Iṣẹ́ Àṣesìnlú Lórílẹ̀-èdè Àméníà Ti Parí Ẹ̀

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣesìnlú lórílẹ̀-èdè Àméníà ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ṣe ojúṣe wọn fún orílẹ̀-èdè wọn. Tẹ́lẹ̀, ṣe ni ìjọba máa ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ́ lọ́dún 2013, orílẹ̀-èdè Àméníà tún òfin ilẹ̀ wọn ṣe, kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lè máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú dípò. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní igba [200] ló ti ń ṣiṣẹ́ àṣesìnlú di bá a ṣe ń sọ yìí. Nígbà tó fi máa di ìparí oṣù June ọdún 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlógún [16] ti parí iṣẹ́ tí wọ́n fi sin orílẹ̀-èdè wọn.

Iṣẹ́ Àṣesìnlú Náà Ń Lọ Dáadáa

Ẹ̀wọ̀n ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kọ́kọ́ parí iṣẹ́ àṣesìnlú yìí wà tẹ́lẹ̀. Torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun ni wọ́n ṣe jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Àmọ́, nígbà tí ìjọba ṣòfin tuntun ni wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí yìí kúrò lẹ́wọ̀n pé kí wọ́n lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣesìnlú. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní January 2014. Wọ́n ń tún àyíká ṣe, wọ́n ń gbá ojú ọ̀nà, wọ́n ń ṣèrànwọ́ láwọn ilé ìwòsàn, wọ́n sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì.

Inú àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ti parí iṣẹ́ àṣesìnlú wọn yìí dùn gan-an pé ìjọba fún wọn láǹfààní láti sìnlú láwọn ọ̀nà tó máa ṣe àwọn aráàlú láǹfààní, bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n ṣe ń tún ìlú ṣe, tí wọ́n sì ń tọ́jú àwọn aláìní. Ètò tuntun tí ìjọba ṣe yìí máa jẹ́ káwọn ọ̀dọ́kùnrin tó bá ti parí iṣẹ́ àṣesìnlú wọn lè pa dà máa ṣe iṣẹ́ gidi nílùú, kò sì ní sí pé ẹnikẹ́ni ń fojú ọ̀daràn wò wọ́n.

Ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ni Davit Arakelyan, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún [22] ti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ tí mo ṣe sìnlú ti jẹ́ kí n túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ kára, kí n túbọ̀ wúlò láwùjọ, kí n sì máa fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan. Inú mi dùn pé mo lè ṣe ojúṣe mi fún orílẹ̀-èdè mi lọ́nà tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní gan-an. Kódà, àwọn ọ̀gá ilé ìtọ́jú náà àtàwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀, títí kan àwọn tó ń gbàtọ́jú máa ń yìn wá fún iṣẹ́ tá à ń ṣe.” Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Pàjáwìrì ni wọ́n pín Mikhayil Manasyan tóun náà jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún [22] sí. Ó sọ pé: “Mo kọ́ nǹkan tuntun bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ sin ìjọba, mo sì lè máa fi ohun tí mo kọ́ ṣiṣẹ́ ṣe báyìí. Mo tún lè ṣe ojúṣe mi fún orílẹ̀-èdè mi láìṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn mi.”

Ṣé Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ ní Àméníà Lè Mú Káwọn Orílẹ̀-èdè Míì Náà Fọwọ́ sí Iṣẹ́ Àṣesìnlú?

Ẹnu àìpẹ́ yìí ni ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà gbé ìgbésẹ̀ láti tún òfin ilẹ̀ wọn ṣe, kí òfin má bàa fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àpilẹ̀kọ 41(3) nínú òfin tí wọ́n tún ṣe, èyí tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní December 2015 sọ pé: “Gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tí ẹ̀sìn rẹ̀ tàbí ohun tó gbà gbọ́ bá ta ko iṣẹ́ ológun ní ẹ̀tọ́ láti ṣiṣẹ́ àṣesìnlú tí òfin fọwọ́ sí.” Àjọ ti ìlú Venice tó wà lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù gbóríyìn fún ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà torí ohun tí wọ́n ṣe yìí, àjọ náà sọ pé wọ́n ṣe dáadáa gan-an bí wọ́n ṣe tẹ̀ lé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá lórí ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Bayatyan nínú ẹjọ́ Bayatyan v. Àméníà, * ó sì yẹ ká yìn wọ́n.

Ètò iṣẹ́ àṣesìnlú tí ìjọba ṣe lórílẹ̀-èdè Àméníà bá ohun tí ìjọba àpapọ̀ fọwọ́ sí mu. Orílẹ̀-èdè Àméníà ò fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun mọ́ báyìí, wọ́n ti fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá gbà wọ́n láyè. Àǹfààní wà nínú ètò tí ìjọba ṣe yìí, àpẹẹrẹ tó dáa ni èyí sì jẹ́ fáwọn orílẹ̀-èdè míì tí ìjọba ti ń fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ohun tí ìjọba ṣe lórílẹ̀-èdè Àméníà fi hàn pé, àti ìjọba, àti aráàlú ni iṣẹ́ àṣesìnlú máa ṣe láǹfààní.

Ọ̀gbẹ́ni Tigran Harutyunyan gbẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Àméníà sọ̀rọ̀, ó ní: “Inú wa dùn pé ìjọba orílẹ̀-èdè Àméníà ti ṣe àwọn ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn aráàlú lójú, títí kan ẹ̀tọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ẹni ò bá jẹ́ kó ṣe é. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè Àméníà máa wá lè ṣe ojúṣe wọn fún ìjọba lọ́nà tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní, tí kò sì ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn.”

^ ìpínrọ̀ 8 Bayatyan v. Àméníà ([GC], no. 23459/03, ECHR 2011) ni ẹjọ́ tí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá. Ọ̀kan pàtàkì ni ẹjọ́ yìí jẹ́ torí pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Ilé Ẹjọ́ máa dájọ́ pé Àpilẹ̀kọ 9 nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn (èyí tó sọ̀rọ̀ nípa òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn) fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣe é.