Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn tó ń wà ibi ìsádi ní Lóvua ń gbádùn àpéjọ àyíká tí wọ́n ṣe lédè Tshiluba

SEPTEMBER 12, 2019
ÀǸGÓLÀ

Àwọn Àpéjọ Tá A Ṣe Ní Orílẹ̀-Èdè Àǹgólà Ní Ibùdó Àwọn Tó Ń Wá Ibi Ìsádi Ní Èdè Lingala àti Tshiluba

Àwọn Àpéjọ Tá A Ṣe Ní Orílẹ̀-Èdè Àǹgólà Ní Ibùdó Àwọn Tó Ń Wá Ibi Ìsádi Ní Èdè Lingala àti Tshiluba

Ní May 25 àti 26, 2019, a ṣé àpéjọ àyíká “Jẹ́ Alágbára!” ní èdè Lingala àti Tshiluba ní ibùdó àwọn tó ń wà ibi ìsádi to wà nílùú Lóvua. Ibùdó yìí fi kìlómítà ẹgbẹ̀rún kan àti méjìlélógún (1,022) jìn sí Luanda, tó jẹ́ olú ìlú Àǹgólà. Nígbà tá a ṣe àpéjọ yẹn, akéde ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (177) tó fi mọ́ àwọn ìdílé wọn ló wà ní ibùdó Lóvua. Síbẹ̀, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́rin (380) èèyàn ló gbádùn àpéjọ tá a ṣe ní èdè Lingala, àwọn mẹ́ta sì ṣe ìrìbọmi. Nígbà tó jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n (630) èèyàn ló gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a ṣe ní èdè Tshiluba, àwọn mẹ́fà sì ṣe ìrìbọmi.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tó sá wá sí Lóvua ṣe bẹ́ẹ̀ torí ìwà ipá tí ò mú kí ìlú fara rọ ní orílẹ̀-èdè Kóńgò. Àwọn ará wa tó wà ní Lóvua ò lè lọ́ sí àwọn ìlú míì láti ṣe ìpàdé, torí wọ́n fòfin de àwọn tó wà ní ibùdó láti rìnrìn àjò. Torí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò pé kí wọ́n ṣe àpéjọ yẹn nínú ibùdó náà, wọ́n sì tún kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì tó ṣe é lò fúngbà díẹ̀. Ìjọ mẹ́rin ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba méjèèjì yìí, mẹ́ta ní èdè Tshiluba àti ọ̀kan ní èdè Lingala

Ní May 24, 2019, alábòójútó àyíká àti aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì rìnrìn àjò lọ sí ibùdó Lóvua kí wọ́n lè rí i pé pèpéle àti ẹ̀rọ tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ wà létòlétò. Láìka àwọn ìpèníjà tí àwọn ara wa tó wà ni ibùdó àwọn tó ń wà ibi ìsádi ń kojú sí, síbẹ̀ wọ́n fi àwọn nǹkan bíi tapólì, òpó, okùn, ìṣó àtàwọn ohun èlò míì tí wọ́n nílò ṣètìlẹ́yìn.

Lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, arákùnrin Honoré Lontongo, tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní Tshiluba nínú ibùdó àwọn tó ń wà ibi ìsádi náà, sọ pé: “Bí a ṣe rí àwọn àpéjọ tá a ṣe nínú ibùdó àwọn tó ń wà ibi ìsádi yìí, láìka àwọn ipò tí kò rọrùn rárá tá a wà sí, jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kì í ṣe àwùjọ wa lódindi nìkan ló nífẹ̀ẹ́, àmọ́, ó tún nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú. Inú mi dùn gan-an!”

A ò ní dákẹ́ àdúrà fún àwọn ara wa tí wọ́n ṣí kúrò níbi tí wọ́n ń gbé torí ìlú tí kò fara rọ àti rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. A mọ̀ pé Jèhófà a máa bá a lọ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí àtàwọn ohun tí wọ́n nílò láti gbé ìgbàgbọ́ wọn ró láìka ibi yòówù kí wọ́n wà sí.​—⁠Róòmù 8:​38, 39.

 

Àwọn arákùnrin ń ṣètò pèpéle àti ẹ̀rọ tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́

Àwọn mẹ́fà tó fẹ́ ṣèrìbọmi dìde dúró láti dáhùn ìbéèrè tí wọ́n máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká tí wọ́n ṣe lédè Tshiluba

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń sọ èdè Lingala ń fẹsẹ̀ rìn lọ sí odò ìrìbọmi tó jẹ́ ìrìn kìlómítà méjì (1.2 máìlì) láti àgọ́ ìsádi tí wọ́n ń gbé

Arákùnrin Johannes De Jager, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Àǹgólà ya fọ́tò pẹ̀lú àwọn ará tó ń sọ èdè Lingala lẹ́yìn àpéjọ náà