Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 29, 2017
ÀǸGÓLÀ

Wọ́n Tú Èéfín Olóró sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àpéjọ Àgbègbè Lórílẹ̀-èdè Àǹgólà

Wọ́n Tú Èéfín Olóró sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Àpéjọ Àgbègbè Lórílẹ̀-èdè Àǹgólà

Ní àárọ̀ Friday, August 25, 2017, nígbà tí àpéjọ àgbègbè ń lọ lọ́wọ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Viana nílùú Luanda, lórílẹ̀-èdè Angola, àwọn irínwó ó lé márùn-ún [405] nínú àwọn tó wá ṣèpàdé ló dákú nígbà tí àwọn kan tú èéfín olóró sínú afẹ́fẹ́. Wọ́n tú èéfín olóró yìí sáàárín èrò, wọ́n sì tú u sáwọn ilé ìtura tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà. Àmọ́, èéfín náà kì í ṣe èyí tó ń gbẹ̀mí èèyàn, torí náà, kò sẹ́ni tó kú. Wọ́n gbé àwọn tí èéfín ọ̀hún pa lára lọ sílé ìwòsàn tó wà nítòsí, wọ́n sì tọ́jú wọn. Láàárín wákàtí díẹ̀, ara èyí tó pọ̀ jù lára wọn ti le tó láti kúrò ní ilé ìwòsàn. Àwọn aláṣẹ ìlú ti ń ṣèwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Wọ́n mú àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan, wọ́n sì mú wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá ní ọ̀sán Friday.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílùú Luanda sọ pé ara gbogbo àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún bá ti ń kọ́fẹ pa dà. Ẹ̀rù ò bá gbogbo àwọn tó wà nípàdé náà, gbogbo wọn ló sì pawọ́ pọ̀ tọ́jú àwọn tọ́rọ̀ bá. Àwọn ará tẹ̀ lé àbá táwọn ọlọ́pàá fún wọn, wọ́n ò sì ṣe ìpàdé ọ̀sán Friday. Àmọ́ lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, wọ́n ń bá àpéjọ àgbègbè wọn lọ, kò sì fi bẹ́ẹ̀ síṣòro kankan ní Saturday, August 26, àti Sunday, August 27. Iye àwọn tó wá lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000], àwọn igba ó dín méjìlá [188] ló ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Àǹgólà: Todd Peckham, +244-923-166-760