Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 30, 2019
AZERBAIJAN

Àpéjọ Agbègbè Mánigbàgbé Wáyé Ní Azerbaijan

Àpéjọ Agbègbè Mánigbàgbé Wáyé Ní Azerbaijan

Ní July 26 sí 28 2019, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan ṣe àpéjọ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún ní Darnagul Ceremony House ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n ń pé ní Baku. Lọ́dún yìí tí ọ̀wọ́ àpéjọ àgbáyé mánigbàgbé wáyé, àpéjọ agbègbè tó wáyé ní Baku pẹ̀lú jẹ́ mánigbàgbé ní ti pé òun ni àpéjọ tó tóbi jù lọ tá a ṣe ní Azerbaijan. Bákan náà, fún ìgbà àkọ́kọ́, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Azerbaijan àti ti Rọ́ṣíà ní orílẹ̀ èdè yẹn pàdé pọ̀ fún àpéjọ kan ṣoṣo.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo akéde tó wà ni Azerbaijan kò ju ẹgbẹ̀rún kan àtààbọ̀ (1,500) lọ, síbẹ̀ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn àti méjìdínlógójì (1,938) ló wá sí àpéjọ yìí. Èèyàn mẹ́tàlélọ́gbọ́n (33) ló sì ṣe ìrìbọmi. Wọ́n fún Arákùnrin Mark Sanderson ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti wọlé sí orílẹ̀-èdè yìí kó lè sọ àsọyé ní àpéjọ náà. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ṣe àpéjọ pẹ̀lú àwọn ará ní Azerbaijan. A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ fún ànfààní yìí.

Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ń jẹ́rìí lọ́nà tó wúni lórí. Olùdarí ibi tá a lò fún àpéjọ náà kíyè sí i pé àlàáfìà, ìfẹ́ àti inú rere jọba láàárin àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà àpéjọ náà àti pé wọ́n ń fi ohun tí wọn ń wàásù ṣèwà hù.

Bó tìẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n ṣì ń fojú òmìnira ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbolẹ̀ ní Azerbaijan, látìgbàdégbà làwọn aláṣẹ ń fún àwọn ará wa lómìnira tó pọ̀ sí i láti jọ́sìn. Ní November 2018, ìjọba Azerbaijan fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láàyè láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Baku. Èyí ló sì fún àwọn ará wa ní òmìnira tó pọ̀ sí i lábẹ́ òfin láti jọ́sin ní gbangba ní ìlú náà.

A bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Azerbaijan yọ̀ fún àwọn ohun rere àti ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nínú ìtàn wọn. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún ìsapá wa “bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin” ní ibi gbogbo lórílẹ̀-èdè Azerbaijan àti kárí ayé.​—Fílípì 1:7.