SEPTEMBER 29, 2020
AZERBAIJAN
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ilẹ̀ Yúróòpù Ṣe Ìpinnu Méjì Tó Dá Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre ní Azerbaijan
Ní September 24, 2020, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe ìpinnu pàtàkì méjì tó dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre ní Azerbaijan. Ìpinnu àkọ́kọ́ dá lórí ẹjọ́ tó wà láàárín ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan àti Arákùnrin Valiyev àtàwọn míì (Valiyev and Others v. Azerbaijan), ìkejì sì dá lórí ẹjọ́ tó wà láàárín ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn (Religious Community of Jehovah’s Witnesses v. Azerbaijan). Ìpinnu yìí á jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará wa láti jọ́sìn bí wọ́n ṣe fẹ́.
Ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan sọ pé àwọn jẹ̀bi ẹ̀sùn méjèèjì, wọ́n sì gbà pé ṣe làwọn fi ẹ̀tọ́ àwọn ará wa dù wọ́n. Wọ́n wá pinnu láti san owó gbà-má-bínú tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ ààbọ̀ náírà ($22,146 U.S.). Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn fara mọ́ ọn pé ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan jẹ̀bi lóòótọ́, wọ́n sì fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n pinnu láti ṣe.
Ọdún 2011 ni wọ́n gbé ẹjọ́ àkọ́kọ́ (Valiyev and Others v. Azerbaijan) lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Àwọn ará wa tó wà nílùú Ganja lọ̀rọ̀ yẹn sì kàn. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn aláṣẹ ìlú yẹn ò fi fọwọ́ sí i pé káwọn ará wa forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn agbófinró máa ń wá síbi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn, tí wọ́n á dabẹ̀ rú, tí wọ́n á fi gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ sátìmọ́lé, tí wọ́n á sì bu owó ìtanràn gọbọi lé àwọn kan lára wọn. Léraléra ni wọ́n dẹ́bi fún arákùnrin kan, tí wọ́n sì ń bu owó ìtanràn lé e, àròpọ̀ iye tí arákùnrin yẹn san ju mílíọ̀nù mẹ́rin lọ (ìyẹn nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ààbọ̀ dọ́là nígbà yẹn). Kódà wọ́n ti ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọ́lé, torí wọn ò rówó tí wọ́n á fi san owó ìtanràn gọbọi tí ìjọba ní kí wọ́n san.
Ọdún 2013 làwọn ará wa gbé ẹjọ́ kejì (Religious Community of Jehovah’s Witnesses v. Azerbaijan) lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ìdí tí wọ́n sì fi pe ẹjọ́ náà ni pé, Ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ò gbà káwọn ará wa kó iye ìtẹ̀jáde tí wọ́n nílò wọ orílẹ̀-èdè náà.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé látìgbà tí wọ́n ti pe ẹjọ́ yìí, ìjọba ò gbà ká forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Ganja, síbẹ̀ nǹkan ti ń yí pa dà díẹ̀díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ará wa ń ṣèpàdé láwọn àwùjọ kéékèèké láìjẹ́ pé àwọn agbófinró ń dà wọ́n láàmú. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba ti gbà káwọn ará kó iye ìtẹ̀jáde tí wọ́n nílò wọ orílẹ̀-èdè náà, àmọ́ ìjọba ṣì máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde náà.
Arákùnrin Kiril Stepanov, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Azerbaijan sọ pé: “Àdúrà wa ni pé kí ìdájọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe yìí mú kó rọrùn fún wa láti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Ganja àti láwọn ìlú míì lórílẹ̀-èdè Azerbaijan. A sì ń retí pé láìpẹ́, ìjọba ò ní máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde wa ká tó kó wọn wọlé.”
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtìlẹyìn rẹ̀. Bí ilé ẹjọ́ ṣe dá wa láre yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé kò sí ‘ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí àwa èèyàn Ọlọ́run tó máa ṣàṣeyọrí.’—Àìsáyà 54:17.