Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 13, 2016
AZERBAIJAN

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Owó Ìtanràn tí Ilé Ẹjọ́ Bù Lé Wọn Torí Pé Wọ́n Ń Sọ Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Pe Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Lórí Owó Ìtanràn tí Ilé Ẹjọ́ Bù Lé Wọn Torí Pé Wọ́n Ń Sọ Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́

Ní December 2, 2016, àwọn aláṣẹ ní Àgọ́ Ọlọ́pàá Ìlú Goranboy lórílẹ̀-èdè Azerbaijan mú Ziyad Dadashov tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sílé ẹjọ́ torí pé ó ń ṣe ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ọkùnrin mẹ́rin tó jẹ́ ará abúlé Ọ̀gbẹ́ni Dadashov jẹ́rìí sí i pé ohun tó gbà gbọ́ ló sọ fáwọn èèyàn, tó sì fún wọn ní ìwé tó dá lórí Bíbélì. Àmọ́, Shirzad Huseynov tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Goranboy sọ pé ó jẹ̀bi, pé ohun tó ń ṣe ta ko òfin, * ó sì bu owó ìtanràn lé e. Owo tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́rìndínláàádọ́ta [846] owó dọ́là ni adájọ́ ní kó san. Ọ̀gbẹ́ni Dadashov ò gbà pé ó yẹ kí wọ́n fìyà jẹ òun lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Lágbègbè kan náà, Jaarey Suleymanova àti Gulnaz Israfilova tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ sí ilé obìnrin kan tí wọ́n ti jọ ń sọ̀rọ̀ Bíbélì fún ọ̀pọ̀ oṣù, obìnrin náà sì máa ń gbádùn ọ̀rọ̀ wọn. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn aláṣẹ ní Àgọ́ Ọlọ́pàá Ìlú Goranboy fẹ̀sùn kan àwọn obìnrin méjèèjì pé ibi tí wọ́n ti ṣe ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn yìí “kò sí lábẹ́ àgbègbè ibi tófin fọwọ́ sí pé kí wọ́n ti máa ṣe ẹ̀sìn wọn.” Nígbà tó sì di November 17, 2016, Ismayil Abdurahmanli tó jẹ́ adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Goranboy bu owó ìtanràn lé àwọn méjèèjì. Ó ní kí àwọn méjèèjì san owó tó tó ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún kan ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n [1,128] owó dọ́là. Àwọn obìnrin yìí náà máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Ọ̀gbẹ́ni Jason Wise, tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kárí ayé sọ pé: “Báwọn aláṣẹ ṣe ń ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Azerbaijan fi hàn pé wọn ò ka àdéhùn European Convention sí rárá. Ohun táwọn aláṣẹ ń ṣe ní àgbègbè Goranboy ta ko òfin tó wà nílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn, tí ìjọba sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé.”

^ ìpínrọ̀ 1 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ nílùú Baku, tó jé olú-ìlú orílẹ̀-èdè Azerbaijan. Wọ́n ní Ọ̀gbẹ́ni Dadashov rú òfin ìjọba, Àpilẹ̀kọ 515.0.4 òfin náà sọ pé kò bófin mu káwọn èèyàn máa ṣe ẹ̀sìn “níbi tí kò sí lábẹ́ àgbègbè ibi tófin fọwọ́ sí pé kí wọ́n ti máa ṣe ẹ̀sìn wọn.”