Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova nílùú Baku

DECEMBER 11, 2017
AZERBAIJAN

Ilé Ẹjọ́ Lórílẹ̀-èdè Azerbaijan Ní Kí Wọ́n Sanwó Gbà-máà-bínú fún Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova

Ilé Ẹjọ́ Lórílẹ̀-èdè Azerbaijan Ní Kí Wọ́n Sanwó Gbà-máà-bínú fún Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova

Ní August 4, 2017, ilé ẹjọ́ kan nílùú Baku, lórílẹ̀-èdè Azerbaijan fọwọ́ sí i pé kí wọ́n sanwó gbà-máà-bínú fún Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé àwọn aláṣẹ fi wọ́n sẹ́wọ̀n oṣù mọ́kànlá [11] láìtọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó tí wọ́n san fún wọn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyà tí wọ́n jẹ lẹ́wọ̀n, ìpinnu tí ilé ẹjọ́ yẹn ṣe fi hàn pé ṣe làwọn aláṣẹ dá wọn lẹ́bi láìnídìí, wọ́n fìyà jẹ wọ́n, wọ́n kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn, wọ́n sì ba àwọn obìnrin yìí lórúkọ jẹ́.

Bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ṣe Dá Wọn Láre Mú Kí Wọ́n Béèrè fún Owó Gbà-Máà-Bínú

Ní February 8, 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Azerbaijan dá Arábìnrin Zakharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova láre ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n ń pín ìwé ẹ̀sìn kiri láìgba àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba. Ilé Ẹjọ́ rí i pé ìjọba ti fọwọ́ sí i pé wọ́n lè kó ìwé tí àwọn obìnrin yìí ń pín, ìyẹn ìwé Kọ́ Ọmọ Rẹ, wọ̀lú, ọ̀rọ̀ inú ìwé náà ò sì ṣèpalára fáwọn aráàlú. Yàtọ̀ síyẹn, Ilé Ẹjọ́ rí i pé àwọn obìnrin yẹn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì. Ohun tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbé ìpinnu tí wọ́n ṣe kà ni ohun tí Òfin Orílẹ̀-èdè Azerbaijan ti sọ pé àwọn ò ní fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du aráàlú àtàwọn ìwé tí ìjọba ilẹ̀ náà ti tọwọ́ bọ̀ lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé.

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ pé kí ilé ẹjọ́ tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àdúgbò bójú tó ọ̀rọ̀ owó gbà-máà-bínú ọ̀hún. Ni Arábìnrin Zakharchenko àti Arábìnrin Jabrayilova bá gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́ Baku City Nasimi District Court, wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ bá àwọn gba owó gbà-máà-bínú lọ́wọ́ Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìnáwó torí pé àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìlú (àti aṣíwájú wọn, ìyẹn Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò) fìyà jẹ àwọn gan-an. Àwọn obìnrin méjèèjì ló wà nílé ẹjọ́ lọ́jọ́ yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara Arábìnrin Zakharchenko ò yá. Shahin Abdullayev, adájọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ náà, gbà wọ́n láyè kí wọ́n ṣàlàyé ohun tójú wọn rí ní ṣókí.

Ilé Ẹjọ́ Gbà Pé Àwọn Aláṣẹ Fìyà Jẹ Àwọn Obìnrin Yìí Láìtọ́

Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ yẹn ṣe jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ti tọwọ́ bọ̀wé pé àwọn ò ní fi ẹ̀tọ́ táwọn aráàlú ní lábẹ́ òfin dù wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun táwọn obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fẹ́ fún wọn déwọ̀n àyè kan. Ilé ẹjọ́ ni kí wọ́n fún Arábìnrin Zakharchenko, tí ọ̀rọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀ gan-an ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlógójì owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($5,737 U.S.), wọ́n sì fún Arábìnrin Jabrayilova tí ọjọ́ orí ẹ̀ ò tó ti ẹni àkọ́kọ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìdínlọ́gbòn owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($4,828 U.S.). Ohun tí ilé ẹjọ́ sọ rèé: “Ilé Ẹjọ́ gbà pé wọ́n fìyà jẹ àwọn olùpẹ̀jọ́ yìí láìtọ́, wọ́n tún fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n láìsí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, èyí sì ti ṣàkóbá fún àwọn olùpẹ̀jọ́ yìí.”

Ni Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìnáwó bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe ní kí wọ́n sanwó fáwọn obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì yìí. Àmọ́ ní November 20, 2017, Ilẹ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn nílùú Baku fagi lé ẹjọ́ tí wọ́n pè, wọ́n ní àwọn fara mọ́ ìpinnu tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe.

Ṣé Ìpinnu Tí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Yìí Máa Nípa Rere?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Azerbaijan ò yéé jọ́sìn Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ń fi òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí lábẹ́ òfin dù wọ́n gan-an, wọ́n sì ń fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Àwọn èèyàn ò yéé halẹ̀ mọ́ wọn, àwọn aláṣẹ ń bu owó ìtanràn lé wọ́n, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n tí wọ́n bá rí wọn níbi tí wọ́n kóra jọ sí láti jọ́sìn tàbí níbi tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Ìjọba ò tíì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú gẹ́gẹ́ bí àfidípò fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Bákan náà, àwọn aláṣẹ ò gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn ibòmíì yàtọ̀ sílùú Baku forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ẹjọ́ méjìdínlógún [18] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ló ṣì wà ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, ìgbà mọ́kànlá [11] sì ni wọ́n ti kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè láti fẹjọ́ ìjoba sùn lórí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Azerbaijan lọ́nà àìtọ́.

Kárí ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń retí pé káwọn ìpinnu tí àwọn ilé ẹjọ́ ń ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí sún àwọn aláṣẹ láti jáwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn tó wà ní Azerbaijan dù wọ́n.