MAY 8, 2018
AZERBAIJAN
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-Èdè Azerbaijan Gbà Kí Wọ́n Sanwó Ìtanràn fún Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova
Ní April 16, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Azerbaijan fara mọ́ ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré kan dá tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n sanwó ìtanràn fún Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova lórí bí wọ́n ṣe fi wọ́n sẹ́wọ̀n oṣù mọ́kànlá láìtọ́. Ṣáájú ìgbà yẹn, lóṣù February, ọdún 2017, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dá àwọn obìnrin náà láre pé wọn ò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n ń pín ìwé ìsìn láìgbàṣẹ lọ́wọ́ Ìjọba. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ wá fi ọ̀rọ̀ sísan owó ìtanràn tí wọ́n béèrè sílẹ̀ sọ́wọ́ ilé ẹjọ́ ìjọba.
Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ ti dá Omidan Zakharchenko àti Omidan Jabrayilova, tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láre gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ ìjọba bá àwọn béèrè owó ìtanràn nítorí ìwà ìkà tí wọ́n hù sí wọn. Ní August 2017, ilé ẹjọ́ agbègbè náà sọ pé ó yẹ kí wọ́n sanwó ìtanràn fún àwọn méjèèjì yìí, àmọ́ Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Owó pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí ọ̀rọ̀ náà. Ní November 2017, ilé ẹjọ́ tó ń gbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn fara mọ́ ìpinnu tí ilé ẹjọ́ agbègbè ṣe. Àmọ́ Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Owó fárí gá, wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ náà, ó di Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní February 2018. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kọ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Owó pè, ó sì fara mọ́ ìdájọ́ tó ti ṣe tẹ́lẹ̀, pé kí wọ́n sanwó ìtanràn fún àwọn obìnrin méjèèjì.
Yàtọ̀ sí pe kí wọ́n sanwó ìtanràn fáwọn obìnrin yìí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbà pé àwọn aláṣẹ ti kọjá àyè wọn nínú ohun tí wọ́n ṣe sí Omidan Zakharchenko àti Omidan Jabrayilova, wọ́n sì ti fi ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin tí ò mọwọ́mẹsẹ̀ yìí dù wọ́n.