Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 22, 2018
AZERBAIJAN

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Forúkọ Ẹ̀sìn Wọn Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin Nílùú Baku, ní Azerbaijan

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Forúkọ Ẹ̀sìn Wọn Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin Nílùú Baku, ní Azerbaijan

Ní November 8, 2018, Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Iṣẹ́ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́sìn ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan fọwọ́ sí i káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin délẹ̀délẹ̀ nílùú Baku, tó jẹ́ olú-ìlú Azerbaijan. Àwọn ará wa ti wá ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lábẹ́ òfin láti máa jọ́sìn ní gbangba, kí wọ́n sì máa wàásù fàlàlà ní ìlú náà.

Àdúrà wa ni pé àṣeyọrí tá a ṣe lábẹ́ òfin yìí máa jẹ́ káwọn aláṣẹ gbà káwọn ará wa tó wà láwọn ibòmíì lórílẹ̀-èdè náà forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé àwọn aláṣẹ fojúure hàn sí wa, wọ́n sì fọwọ́ sí i kí òfin gbà wá láyè láti máa ṣe ìjọsìn wa nílùú Baku.​—Fílípì 1:7.