APRIL 16, 2021
BELGIUM
Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021—Iye Àwọn Tó Wá sí Ìrántí Ikú Kristi ní Belgium Lọ́dún Yìí Pọ̀ Ju ti Àtẹ̀yìnwá Lọ
Lọ́dún 2021, àwọn ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádọ́ta àti ogójì (49,040) ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi lórílẹ̀-èdè Belgium. Ìrántí Ikú Kristi ni ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún. Iye yìí ló tíì pọ̀ jù tá a bá fi wé iye àwọn tó ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi ní Belgium látọdún 1995. Iye yẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà.
Ohun tó mú kí èyí jọni lójú ni pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ní Belgium ni ò ṣe ẹ̀sìn kankan mọ́. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 1970, ohun tó ju ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá ló sọ pé Kristẹni làwọn. Tá a bá sì kó èèyàn ọgọ́rùn-ún (100) jọ, agbára káká la fi máa rí àwọn méje tó máa sọ pé àwọn ò ṣe ẹ̀sìn kankan. Àmọ́, ìròyìn ẹnu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn tó jẹ́ Kristẹni lórílẹ̀-èdè Belgium kò tó ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá mọ́. Bákan náà, àwọn tí ò ṣe ẹ̀sìn kankan ti lé ní ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá.
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn oníròyìn ní Belgium ti sọ ọ̀pọ̀ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láìka àwọn ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ yìí sí, ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè náà túbọ̀ ń wá ìsọfúnni tó jóòótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ló ń fojú ara wọn rí ìfẹ́ tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà, wọ́n sì tún ń rí bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ń tún ayé wọn ṣe.—Jòhánù 13:35.
Ní February 2021, ìròyìn tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Belgium fi hàn pé àwọn ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́rin (11,804) làwọn ará wa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ju ìpíndọ́gba iye àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. Ní ìpíndọ́gba, láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún tí wọ́n sì ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ ní Belgium yìí jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ṣe ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré sì máa di orílẹ̀-èdè alágbára.”—Àìsáyà 60:22.