Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Bọ̀géríà tó wà ní ìlú Sofia

MAY 20, 2019
BỌ̀GÉRÍÀ

Àwọn Ẹjọ́ Tá A Jàre Nílé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Dáàbò Bo Ẹ̀tọ́ Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn ní Bọ̀géríà

Àwọn Ẹjọ́ Tá A Jàre Nílé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Dáàbò Bo Ẹ̀tọ́ Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn ní Bọ̀géríà

Lóṣù March 2019, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Bọ̀géríà dá àwọn ará wa láre nínú ẹjọ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ẹjọ́ tó lápẹẹrẹ yìí máa wúlò gan-an láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ táwọn ará wa ní láti ṣe ẹ̀sìn wọn káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Nínú méjì lára àwọn ẹjọ́ náà, ńṣe làwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbéròyìn jáde parọ́ mọ́ àwọn ará wa. Lọ́dún 2012, ìwé ìròyìn Vseki Den gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tó fi sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ohun tá a gbà gbọ́. Bákan náà, lọ́dún 2014, ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n SKAT TV gbé ìròyìn èké jáde nípa ètò wa. Nígbà táwọn ará wa sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣàtúnṣe sí irọ́ tí wọ́n pa mọ́ wa, ńṣe ni ilé iṣẹ́ méjèèjì kọ̀ jálẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tá a pè, títí dé àwọn ilé ẹjọ́ kòtẹ́miọ́rùn, a gbé àwọn ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ. Ní March 18, 2019 Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n SKAT TV lẹ́bi. Ní March 26, Ilé Ẹjọ́ yìí tẹ̀ lé ìpinnu rẹ̀ nínú ẹjọ́ àkọ́kọ́, ó sì dẹ́bi fún ìwé ìròyìn Vseki Den pé ó lo “ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó kórìíra.”

Ẹjọ́ kẹta dá lé ìwà ìkà táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú VMRO-Bulgarian National Movement hù sáwọn ará wa. Ní April 17, 2011, àwọn ará wa pé jọ láti ṣe Ìrántí ikú Jésù. Àmọ́, ńṣe ni Georgi Drakaliev tó jẹ́ olórí nínú ẹgbẹ́ VMRO kó ọgọ́ta (60) jàǹdùkú jọ, wọ́n wá ṣe àwọn ará lésẹ, wọ́n sì dọ́gbẹ́ sí wọn lára. Àwọn ará gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́. Nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ náà dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ. Ní March 20, 2019, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá Ọ̀gbẹ́ni Drakaliev lẹ́bi, wọ́n sì ní kó sanwó ìtanràn fáwọn ará wa.

Inú wa dùn gan-an torí bá a ṣe jàre nínú ẹjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí. Àwọn ilé ẹjọ́ lè lo àwọn ìdájọ́ tó lápẹẹrẹ yìí láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ táwọn ará wa ní láti “máa gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, bí wọ́n ti ń fi gbogbo ọkàn wọn sin Ọlọ́run.”​—1 Tímótì 2:2.